Ami Ẹyẹ Ibrahim: Ellen Sirleaf gba ami ẹyẹ oludari ni Africa

Ellen johnson sirleaf

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Sirleaf jẹ obinrin akọkọ ti yoo jẹ aarẹ lorilẹ Afirika

Ellen Johnson Sirleaf ti gba ami ẹyẹ Ibrahim ti oludari nilẹ Africa (African Leadership) fun ọdun 2017, pẹlu iye owo ti o to milliọnu marun dọla (180,5000000 naira), lẹyin ti o f'ipo silẹ losu ti o kọja.

Arabinrin Sirleaf jẹ obinrin akọkọ ti yoo jẹ aarẹ lorilẹ Afirika lọdun 2006.

Arabinrin naa ni wọn gboriyin fun wipe o tun orilẹede Liberia ṣe, ti o si sokunfa irẹpọ to pada sorilẹede naa, lẹyin ogun abẹle won.

Ninu ọrọ wọn, ẹgbẹ alami ẹyẹ naa ni bi o tilẹ jẹ wi pe awọn eniyan fẹsun kan aarẹ tẹlẹri naa wipe o f'aaye gba gbigba iwa ibajẹ lawujọ, wọn wipe arabinrin naa lamilaaka nipa fifi ipa adari rere silẹ nigba to wa n'ipo aarẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ orilẹede Mozambique tẹlẹri, Joaquim Chissano ni ẹni akọkọ ti o gba ami ẹyẹ yi ni ọdun 2007

Arabinrin Sirleaf ni aarẹ orilẹede Liberia fun saa meji, ki o to di wipe agbabọọlu tẹlẹri ni, George Weah wa di aarẹ orilẹede naa ninu idibo to kọja lọ.

Amọ, awọn ẹgbẹ oselu rẹ yoo bi jiga kuro ninu ẹgbẹ wọn, nigbati wọn f'ẹsun kan an wipe o se agbatẹru fun George Weah dipo ọmọ ẹgbẹ oselu rẹ.

Lọdun 2011, ajafẹtọ ọmọniyan Laymah Gbowee ati aarẹ Sirleaf nigba to wa nipo, gba ami ẹyẹ agbaye Nobel Peace prize fun dida alaafia pada sorilẹede Liberia.

Ami ẹy Ibrahim

Ami ẹyẹ Ibrahim wa fun igbelarugẹ awọn asaaju orilẹede Afirika to lamilaaka nigba ti wọn wa nipo asaaju.

Ami ẹyẹ yi wa fun awọn olori orilẹede nilẹ Afirika tẹlẹri, ti wọn fi ipo asaaju wọn mu igbega ba orilẹede wọn.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Namibia tẹlẹri, Hifikipunye Pohamba lo gba ami ẹyẹ yi ni ọdun 2014

Igbimọ olominira lo n se isakoso ami ẹyẹ naa.

Awọn to ti gba ami ẹyẹ Ibrahim lati ọdun Mejila sẹyin:

  • 2007: Aarẹ orilẹede Mozambique tẹlẹri, Joaquim Chissano lo gba ami ẹyẹ tọdun naa fun dida alafia, ilaja ati oselu tiwantiwa pada sọrilẹede Mozambique lẹyin ogun abẹle
  • 2008: Aarẹ Botswana tẹlẹri, Festus Mogae lo gba a fun ipa ribiti to ko lati gbogun ti aisan kogboogun HIV/AIDS ti o ba orilẹede naa wọyaaja
  • 2009: Wọn ko fun ẹnikẹni lọdun yi
  • 2010: Wọn ko fun ẹnikẹni lọdun yi
  • 2011: Aarẹ orilẹede Cape Verde tẹlẹri, Pedro Verona Pires lo gba a fun ipa ti o ko lati mu idagbasoke ba ọrọ aje orilẹede naa ati imugboro ijọba tiwantiwa
  • 2012: Wọn ko fun ẹnikẹni lọdun yi
  • 2013: Wọn ko fun ẹnikẹni lọdun yi
  • 2014: Aarẹ Namibia tẹlẹri, Hifikipunye Pohamba lo gba ami ẹyẹ fun aseyọri rẹ nipa dida alaafia pada si orilẹede Namibia, eleyi ti o yọri si imugboro ọrọ aje orilẹede naa
  • 2015: Wọn ko fun ẹnikẹni lọdun yi
  • 2016: Wọn ko fun ẹnikẹni lọdun yi.

Arabinrin Sirleaf jẹ ẹni karun ati obinrin akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ yi lati igba ti wọn ti daa silẹ lọdun 2006.