Idaamu Boko Haram: Igbẹjọ awọn afunrasi bẹrẹ ni gbangba loni

Awon afurasi Boko Haram nile ejo ni Chad Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orilẹede Chad se igbẹjọ ati idajọ fun awọn Boko Haram

Igbẹjọ ọlọgọọrọ eniyan ni gbangba yoo bẹrẹ fun awọn afunrasi ọmọ ikọ Boko Haram loni, (ọjọ aje) ni ile-iṣe awọn ologun ni agbegbe aarin gbungun orilẹede Naijiria, ni ilu Kainji.

Ile-isẹ ijọba to n risi ọrọ igbẹjọ lorilẹede Naijiria, sọ wipe ita gbangba ni wọn yoo ti ṣe igbẹjọ awọn afunrasi to le lẹgbẹrun naa, eleyi ti o yatọ si igbẹjọ ikọkọ ti wọn maa n ṣe fun wọn tẹlẹ.

Igbesẹ tuntun naa waye latari bi awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan, Amnesty International se fajuro si bi ileesẹ ologun se n se igbẹjọ ida kọnkọ fun awọn afunrasi ikọ Boko Haram naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igbẹjọ awọn afunrasi Boko Haram bẹrẹ lojo aje

Akọroyin BBC, Ishaq Kalid sọ wipe awọn afunrasi ti o le lẹgbẹrun naa ti wa latimọle fun ọpọlọpọ ọdun, ati wipe adajọ mẹrin ni yoo gbọ igbẹjọ naa ti yoo waye ni ile-igbẹjọ tiwantiwa ti kii se ti awọn ologun.

Kalid wipe wọn sun igbẹjọ naa siwaju fun osu mẹrin ki wọn le e fun awọn alaṣẹ laaye lati se iwadi finifini lori awọn afunrasi ikọ Boko Haram.

Nigba ti igbẹjọ naa bere losu kẹwa ọdun to kọja, awọn eniyan marundinlaadọta ni wọn s'ẹwọn ọdun mẹta si mọkanlelọgbọn, ti wọn si da awọn igba meji eniyan silẹ nitori ẹsun ti ko lẹsẹ n lẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ikọ ẹṣinokọku Boko Haram ti bẹrẹ idukuku mọni lọdun 2009

Akọroyin BBC naa jabọ pe ẹgbẹgbẹrun awọn afunrasi ikọ Boko Haram ti wọn ṣi wa latimọle awọn ile-iṣẹ ologun kaakiri orilẹede Naijiria, ni o ṣeeṣe ki igbẹjọ wọn naa o waye laipẹ.

Lati igba ti awọn ikọ ẹṣinokọku Boko Haram ti bẹrẹ idukuku mọni lọdun 2009, eniyan ti o le lẹgbẹrun lọna ogun ni wọn ti ran lọ s'ọrun ọsan gangan, ti ọgọọrọ eniyan si ti di alairilegbe nipasẹ awọn igbesunmọmi ati isekupani awọn ikọ Boko Haram lorilẹede Naijiria ati lagbegbe Lake Chad.