Opin Zuma: ANC yoo s'epade lori aarẹ loni

Awọn eniyan nfi ẹhonuhan, wan nfẹ ifiposilẹ Zuma Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iroyin filede wipe, ni kọrọ, aarẹ Zuma n se idunadura lori bi ohun yoo se kuro lori oye

Awọn adari ẹgbẹ oselu ANC lorilẹede South Africa yoo se'pade loni, eleyi ti wọn yoo ti pe fun ifipo silẹ aarẹ Jacob Zuma, akọroyin BBC Andrew Harding jabọ.

Harding nigba ti o n jabọ wipe wakati toku ninu ọjọ oni se koko fun igbesẹ lori boya ija oloselu yoo bẹ silẹ, tabi wọn yoo se ifipo oselu silẹ fẹlomiran ni irọwọ-rọsẹ lorilẹede naa ati wipe n jẹ o seese fun aarẹ Jacob Zuma lati kọ'we f'ipo rẹ silẹ?

Adari tuntun fẹgbẹ oselu ANC, Cyril Ramphosa lọjọ isinmi ti fun aarẹ Jacob Zuma t'o jẹ ọmọ ọdun marundinlọgọrin naa ni gbendeke lati fipo rẹ silẹ tabi ki awọn adari ẹgbẹ o yọọ n'ipo bi wọn ti n yọ jiga.

Awọn adari ẹgbẹ naa yoo se'pade ni ilu Pretoria lati kọ'we si aarẹ naa lati fi ipo silẹ fun Ramphosa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán O seese ki adari tuntun f'ẹgbẹ oselu ANC, Cyril Ramphosa rọpọ̀ Zuma gẹgẹbi aarẹ

Akọroyin BBC naa fikun un wipe ti o ba kọrọ si awọn ẹgbẹ oselu rẹ lẹnu, ile igbimọ asofin lorilẹede South Africa yoo dibo "mi o ni gbagbọ ninu rẹ mọ" fun aarẹ naa.

Iroyin filede wipe, ni kọrọ, aarẹ Zuma n se idunadura lori bi ohun yoo se kuro lori oye. Zuma n koju ẹsun iwa ibajẹ, lilu owo ilu ni ponpo, eleyi ti o ti da rudurudu silẹ laarin ẹgbẹ oselu ANC naa.