Lori ejo to mi owo: Ajọ JAMB fun osisẹ n'iwe lọ gbe'le ẹ

aworan ejo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán osise ajo jamb wipe ejo gbe owo mi

Ajọ JAMB ti kede lana wipe ohun ti fun oṣiṣẹ rẹ̀ Philomina Chieshe niwe lọ gbélé ẹ látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ ejò miwó-miwó ti wọ́n lo mi mílíọ́nù mẹ́rìndínlógóji naira lọ́ọ̀físì ìgbìmọ̀ aláṣẹ àjọ nàá tó wà ní Makurdi ní ìpínlẹ̀ Benue.

Olórí ẹ̀ka ìròyìn f'un àjọ náà, Fabian Benjamin sọ fún àwọn oníròyìn ní ọjọ́ ìsinmi pe ìgbìmọ̀ aláṣẹ ti ń fi ojú rẹ̀ wináà ìjìyà tí o yẹ, àti wípé àwọn iléèṣẹ́ ètò ààbò ti ń ṣe ìwádi lori ọ̀rọ̀ nàá.

Benjamin wi pe, "o ti gba iwe lọ gbele ẹ, o si ti n fi oju winaa ibaniwi pẹlu bi iwadi ṣe n lọ lori ọrọ naa.

Ohun to sọ ni wipe, ejo kan wọ ọọfisi, to si gbe miliọnu mẹrindinlogoji ti wọn pa mi."

Image copyright @JAMB
Àkọlé àwòrán Iroyin fidirẹmulẹ pe ejo ajoji kan mi miliọnu mẹrindinlogoji naira lọọfisi ajọ JAMB

Ìròyin fi idi rẹ mulẹ pe Chieshe sàlàyé pé ejo ajoji kan deede wọ inu ọọfisi ti ajọ JAMB n ko owo si, to si ko miliọnu mẹrindinlogoji naira lọ.

Owo naa ni wọn ni o jẹ eyi ti wọn pa lati ara tita kaadi ẹrọ ayelujara lawọn ileesẹ ajọ naa to n bẹ lawọn ipinlẹ to fi mọ awọn alagbata rẹ.

JAMB f'ọjọ kun asiko iforukosilẹ

Ikọ oluyẹwe owo wo niroyin gbe wipe wọn ran lọ si awọn ọọfisi ajọ naa to n bẹ lawọn ipinlẹ lati lọ ṣe akọsilẹ bi wọn ṣe ta kaadi naa si, ati lati gba owo ti wọn pa.

Lasiko naa ni wọn ni obinrin naa sọ fun ikọ naa wipe oun o le salaye kankan nipa miliọnu mẹrindinlogoji ti wọn pa wọle lawọn ọdun to diẹ sẹyin saaju ki wọn o to dawọ tita kaadi naa duro.

Ṣugbọn, lasiko ti wọn fi ọrọ wa lẹnuwo ni wọn ni obinrin naa pada yi ọrọ pada, to si ni pe ọmọ ọdọ oun ati obinrin kan, Joan Asen lo lo agbara airi lati ji owo naa gbe ni ibudo ti wọn ko owo naa pamọ si.