#NigeriaDecides2019: Awọn oloselu Naijiria ati awọn ẹbun ifẹ wọn

Awọn eniyan tin ju oko ọrọ si Mao Ohuabunwa
Oriṣii ọbẹ la n ri lọjọ ikú erin ni ọrọ ẹbun awọn oloṣelu lasiko idibo.
Laipẹ yi niroyin gbe wi pe Senator to n soju ẹkun idibo ariwa ipinlẹ Abia, MAO Ohuabunwa pin apẹ idinkara fun awọn eniyan lagbegbe to n soju nileegbimọ asofin agba Naijiria.
Ọgọrọ awọn ọmọ Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, bi o ti lẹ jẹ wipe Ohuabunwa ni "oun o kabamọ pinpin apẹ naa" ninu iroyin ti iwe iroyin fi sita.
2019: Wo fídíò bí wọ́n ṣe sọ nǹkan lu àwọn adarí APC l'Abẹokuta
Oríṣun àwòrán, dfxmedia.wordpress.com
Gomina Fayose ti pin orisirisi ẹbun bi irẹsi ati adiyẹ adiyẹ
Kiiṣe Ohuabunwa ni oloselu ti yoo kọkọ pin awọn ẹbun ti a le tọka si bi eyi ti ko bojumu.
Wo awọn oloselu atẹbun arí ṣe haaa!
Oríṣun àwòrán, @SegunOladejo_
Orisirisi ẹbun to mu isọnu dani lawọn oloselu ti pin ni Naijiria
Gomina Ortum ti Benue naa ko gbẹyin ninu ẹbun rẹ
Oríṣun àwòrán, ajayiwrites.blogspot.co.uk
Asofin Shehu Sani n soju ẹkun idibo aarin gbungbun Kaduna
Mao Ohuabunwa n soju ẹkun ariwa ipinle Abia
Oríṣun àwòrán, gistmania.com
Olori ileegbimọ asofin ipinlẹ Ọsun naa pin tii alagbada
Afẹnifẹre ni ọrọ atunto lawọ́n tori ẹ yan Atiku laayo