EFCC gbe oṣiṣẹ ile-ifowopamọsi lọ s'ile ẹjọ

Aworan ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adajọ sun igbẹjọ da ọjọ ẹti, osu keji, ọdun yii fun itẹsiwaju igbẹjọ

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC ti gbe osisẹ ile-isẹ ifowopamọ tẹlẹri, Adejare Sonde re'le ẹjọ giga to wa ni Abeokuta, ni ipinlọẹ Ogun.

Ajọ EFCC ti ẹka ti o wa ni Ibadan fi ẹsun ole jija ati yiyi iwe lori iye owo ti o to milliọnu mẹrinlelọgọfa naira.

Ẹni ti wọn f'ẹsun kan naa, nigba ti o de'waju adajọ, ti orukọ rẹ n jẹ A. A Akinyẹmi, sọ wipe ohun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan ohun.

Latari ẹbẹ rẹ nile ẹjọ, agbẹjọro rẹ ke si ile ẹjọ lati sun igbẹjọ rẹ siwaju, ki o si wa ni atimọle ajọ EFCC titi ti wọn yoo fi gba ẹjọ beeli rẹ.

Adajọ Akinyemi gbọ si agbẹjọro naa lẹnu, o si wipe ki ẹniti wọn f'ẹsun ole kan naa o wa latimọle ajọ EFCC, titi wọn yoo fi gbọ ẹjọ beeli rẹ.

Adajọ sun igbẹjọ si ọjọ ẹti, osu keji, ọdun yii fun itẹsiwaju igbẹjọ naa.