Irinajo Libya: Ijọba apapọ tun ko awọn atipo miran wale

Awon arinrinajo omo Naijiria lati Libya Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ọmọ Naijiria mẹ́rìndínlógóje pada sile lati orilẹede Libya

Ajọ to n mojuto isẹlẹ pajawiri ni Naijiria (NEMA) sọ pe awọn ọmọ Naijiria mẹ́rìndínlógóje mi i ti pada s'ile lati orilẹede Libya.

Awọn asatipo naa de si papakọ ọkọ ofurufu ilu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers ni agogo kan kọja isẹju mẹwa oru oni ọjọ iṣẹgun.

Ajọ NEMA sọ pe ipele karun ni awọn ti o pada wale yii. Wọn ko wọn pẹlu ọkọ ofufuru Medview ni owurọ yi.

Agbẹnusọ fun ajọ naa, Sanni Datti sọ fun BBC Yoruba wipe awọn ṣi n se ayẹwo ati akọsilẹ orukọ wọn lọwọlọwọ bayi lati mọ ipo ti ilera wọn wa.

A o fun un yin ni ẹkun rẹrẹ iroyin yii ti o ba ti tẹ wa lọwọ.