ANC pahunpọ pe ki Zuma f'ipo s'ilẹ

Aarẹ South Africa, Jacob Zuma Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán ANC kọ'we si aarẹ Jacob Zuma lati kọ'we f'ipo rẹ silẹ

Ẹgbẹ oselu to wa lori oye lorilẹede South Africa, ANC ti kọ'we si aarẹ Jacob Zuma lati kọ'we f'ipo rẹ silẹ, awọn oniroyin lo sọ bẹẹ.

Igbesẹ lati yọ aarẹ Zuma naa ko sẹyin ọpọlọpọ ipade idakọnkọ ti awọn olori ninu ẹgbẹ oselu naa se titi di afẹmọjumọ ọjọ iṣẹgun oni.

Iroyin wipe ti aarẹ Zuma ko ba kọ'we f'ipo s'ilẹ, awọn asofin lorilẹede naa yoo d'ibo mi o ni igbẹkẹle ninu rẹ, (vote of no confidence)". Eleyi ti wọn gbagbọ wipe yoo sokunfa ifipo silẹ aarẹ Jacob Zuma.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òṣèlú ANC fẹ́ ki Jacob Zuma o kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ààrẹ South Africa

Ẹgbẹ oselu ANC ko i ti fi abajade ipade rẹ sita, sugbọn lara awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa lo fi ọrọ naa lede fun awọn oniroyin lorilẹede South Africa ati ile isẹ iroyin Reuters News Agency.

Opin Zuma: ANC se'pade lori aarẹ

ANC fẹ yọ Zuma

Lọpọ igba ni aarẹ Zuma ti kọ jalẹ lati kọwe fipo silẹ lori ẹsun iwa ibajẹ ati lilu owo ilu ni ponpo. Eyi to mu ki ẹgbẹ oselu rẹ yan Cyril Ramphosa lati dipo rẹ gẹgẹ bi asaaju ninu ẹgbẹ oselu naa.

Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Awọn alakoso igbimọ pe ipade pajawiri fun ọjọ aje lati jiroro lori Aarẹ Zuma

Amọ, ko i ti di mimọ fun awọn oniroyin bi aarẹ Zuma yoo se fesi si iwe ti wọn kọ sii lati kọwe fipo silẹ.

Iroyin fi lede wipe, olori tuntun fun ẹgbẹ oselu ANC, Cyril Ramphosa kuro nibi ipade ẹgbẹ naa, lati lọ sọ fun aarẹ Zuma wipe ki o tete kọwe fipo silẹ, ki wọn ma ba a le kuro lori oye. Lẹyin naa ni Ramphosa pada sibi ipade idakọnkọ naa.