Ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ogun gba'dajọ ẹwọn

Awọn ọmọ Boko Haram nile ẹjọ ni orilẹede Chad ni 2015 Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Boko Haram ti se iku pa ogunlọgọ eniyan lati ọdun 2013

Ko din ni eeyan ogun ti wọn ti ju s'ẹwọn l'orilẹede Naijiria nitori wipe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ agbesunmmi, Boko Haram.

Idajọ naa waye nibi igbẹjọ aṣepọ to n lọ lọwọ nibudo awọn ologun kan nilu Kainji lori awọn afurasi to le ni ẹgbẹrun kan.

Oniroyin BBC, Is'haq Khalid jabọ iroyin lati Abuja pe:

Ogun eeyan ni wọn fidirẹmulẹ pe o jẹbi awọn ẹsun to niiṣe pẹlu ẹsun igbesunmọmi, ipaniyan ati ijinigbe.

Ẹjọ ẹwọn ọdun mẹta si mẹẹdogun ni wọn da fun wọn.

Ọkan lara awọn ẹjọ to gbaju-gbaja nibi igbẹjọ naa ni ti ọkunrin alaabọ-ara kan ti wọn lo kopa ninu bi wọn ṣe ji awọn akẹkọbinrin to le ni igba gbe nilu Chibok, lẹkun ila-oorun ariwa lọdun 2014.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Idajọ bẹrẹ nilu Kainji lori awọn afurasi to le ni ẹgbẹrun kan

Wọn ti ju ọkunrin naa si ẹwọn ọdun mẹẹdogun.

Igba akọkọ ni yii ti wọn yoo dajọ ẹwọn fun ẹnikẹni lori iwa ijinigbe naa to mi gbogbo agbaye titi.

Nibi igbẹjọ naa, awọn afurasi ẹgbẹ Boko Haram meji ni wọn da silẹ nitori pe ko si ẹri to tako wọn.

Awọn orisun iroyin kan sọ fun BBC pe ẹẹdẹgbẹrin awọn afurasi ni ile ẹjọ ilu mẹẹrin ọtọọtọ yoo f'oju wọn wina ẹjọ nibudo awọn ologun kan to wa niluu Kainji lọsẹ yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wọn ti ju ọkunrin kan si ẹwọn ọdun mẹẹdogun

Awọn alaṣẹ ijọba Naijiria ni awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ Boko Haram to le ni ẹgbẹrun mẹfa lo wa ni ahamọ jakejado orileede Naijiria.

Losu kẹwa, eeyan marunlelogoji lo gba idajọ ẹwọn ọdun mẹta si mọkanlelọgbọn nitori wipe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi naa.