Morgan Tsvangirai di alaisi

Morgan Tsvangirai lọdun 2002 Image copyright AFP

Olori ẹgbẹ oselu alatako, Morgan Tsvangirai ti jade laye lẹni ọdun marundinlaadọrin.

Ikede kan tawọn mọlẹbi fi to igbakeji aarẹ ẹgbẹ oselu MDC, Elias Mudzuri leti salaye pe, Tsvangirai jẹ Ọlọrun nipe nirọlẹ ọjọru nitori aisan jẹjẹrẹ inu eegun to n baa finra.

Itan igbesi aye Tsvangirai

Morgan Tsvangirai, jẹ osisẹ awakusa tẹlẹ ati olori ẹgbẹ osisẹ, oun si lo sedasilẹ ẹgbẹ to n wa iyipada sijọba alagbada lorilẹede Zimbabwe ( Movement for Democratic Change ) (MDC) lọdun 2000, ko to wa pada di asaaju ẹgbẹ oselu alatako to mu yanyan julọ latigba torilẹede naa ti gba ominira.

Amọ sa, nse ni Robert Mugabe maa n ta Tsvangirai yọ ninu gbogbo igbinyanju rẹ, ẹni to faake kọri lati fi ipo agbara silẹ, biotilẹjpe Tsvangirai gba ipo olootu ijọba labẹ isejọba Mugabe ninu isejọba alajumse kan lẹyin eto idibo kan to mu awuyewuye dani lọdun 2008.

Nigba to wa lori aleefa gẹgẹ bii olootu ijọba, o nira fun Tsvangirai lati se aseyọri ninu eto atunto kankan to nitumọ, amọ o ko ipa to giriki nidi lila ọna lati doju isejọba Mugabe bolẹ lọdun 2017.

Lati ori isẹ awakusa bọ si ipo asaaju alatako:

Image copyright AFP
 • A bi lọjọ kẹwa osu kẹta ọdun 1952 nilu Gutu- o jẹ kan lara ọmọ mẹsan ti ọkunrin gbẹnagbẹna kan bi
 • O kuro nileẹkọ lati maa hun asọ, amọ o tun n lọ sisẹ bii awakusa
 • O lọwọ ninu ọrọ ẹgbẹ osisẹ, wọn si yan sipo alasẹ ẹgbẹ apapọ fawọn osisẹ awakusa
 • Lẹyin ominira lọdun 1980, O darapọ mọ ẹgbẹ Zanu-PF to n sejọba, o si di oloye agba ninu ẹgbẹ
 • Lọdun 1988, O di olori ẹgbẹ apapọ osisẹ lorilede Zimbabwe (ZCTU )
 • Losu kejila ọdun 1997 ati nibẹrẹ ọdun 1998, ZCTU lewaju ọpọ iyansẹlodi to seso rere lati tako ele owo ori
 • Ẹgbẹ osisẹ ZCTU yi si lo seranwọ lati sagbekalẹ ẹgbẹ oselu MDC losu kẹsan ọdun 1999
 • Lọdun to tẹle, ẹgbẹ oselu yi ko ijoko mẹtadinlọgọta nile asofin apapọ- to si di ẹgbẹ oselu alatako to dara julọ ti yoo farahan ninu itan orilẹede Zimbabwe

Aloyin lete to dantọ ninu ọrọ araalu, Tsvangirai ati ẹgbẹ oselu rẹ tuntun, MDC, ba ifẹ ọkan awọn ọdọ to wa lawọn ilu to laju lorilẹede Zimbabwe mu, awọn ti oju wọn ti la kuro ninu isejọba ẹlẹgbẹ oselu kansoso ati ọrọ aje to n sojojo.

Amọ nse ni Mugabe ri ẹgbẹ oselu alatako MDC gẹgẹbii ohun eelo lọwọ awọn agbẹ to jẹ oyinbo alawọ funfun ati ijọba ilẹ gẹẹsi, lainaani ipilẹ ẹgbẹ osisẹ ti ẹgbẹ oselu naa ni.

Lẹyin ọdun 2000, Tsvangirai di ami idamọ atako fun Mugabe to n dogbo lọ pẹlu isejọba to n tẹri ẹni ba- to si nkoju ọpọ itimọle, aludojubolẹ ati ẹsun igbinyanju lati doju ijọba bolẹ.

Lainaani okiki to ni gẹgẹ bii ajijagbara, ọpọ awọn alatilẹyin Ọgbẹni Tsvangirai lo ti fẹsun kan-an pe o n huwa bii apasẹ waa nigba mii.

O wọgile ipinnu awọn asaaju ẹgbẹ oselu MDC lati kopa ninu awọn eto idibo sile asofin agba lọdun 2005, to si pasẹ pe ki wọn takete sawọn eto idibo naa.

Eyi sokunfa iyapa ninu ẹgbẹ oselu naa ati ijakulẹ nla lori anfaani to ni lati gba ijọba mọ Mugabe lọwọ.

Lọdun 2007 ni wọn tun mu Tsvangirai lẹẹkan sii, lakoko yi, wọn gbe lọ sawọn bareke pataki to jẹ tawọn agbofinro, nibiti wọn ti na ni anadojubolẹ fun ọpọlọpọ wakati, eyi to mu ko ni ọgbẹ lori, to si n se ẹjẹ sinu.

Wọn gbe lọ sile iwosan abẹle kan nibiti ayaworan kan to n fi isẹ naa se idabọ, Edward Chikomba, ti ya aworan awọn ọgbẹ to ni lori tẹlifisan, to si sa kuro lorilẹede Zimbabwe. Amọ wọn papa fi tipa gbe Chikomba, ti wọn si gbẹmi rẹ.

Itan igbe aye tara rẹ ati ti oselu:

Image copyright AFP
 • Iroyin ni ori ko yọ ninu ete lati gba ẹmi rẹ ni ẹẹmẹta ọtọọtọ, to fi mọ eyi to waye lọdun 1997 nibiti wọn ti gbinyanju lati fẹ fi tipatipa tii bọ silẹ lati oju ferese lati ori ile alaja mẹwa to jẹ ọọfisi rẹ.
 • Awọn alatilẹyin rẹ mọ pẹlu orukọ ẹya rẹ to tumọ si "Paamọ"
 • O bi ọmọ mẹfa ti orukọ akọbi rẹ si n jẹ Susan, ẹni to jalaisi ninu ijamba ọkọ kan to waye lọdun 2009 ni kete to di olootu ijọba
 • "Alaimọkan" ni Mugabe maa n pee nitori pe o jẹ atapatadide ati pe ko ni ẹkọ iwe.
 • O fojuhan losu kẹfa ọdun 2016 pe aisan jẹjẹrẹ inu eegun n baa finra.

Losu kẹta ọdun 2008 o du ipo aarẹ to si ko ọpọ ibo to pọ julọ, sugbọn, gẹgẹ bi esi ibo tawọn alasẹ fisita ti wi, esi ibo rẹ ko to lati bori idibo naa lẹẹkanaa

Ko to di pe wọn se atundi ibo losu kẹfa, awọn osisẹ alaabo Mugabe ti bẹrẹ eto ipolongo ifiyajẹni lori awọn alatilẹyin oloselu alatako, ti Tsvangirai si yọwọ yọsẹ ninu atundi ibo naa.

Wọn kede Mugabe gẹgẹbii ẹni to bori atundi ibo naa, amọ ifẹhonuhan ati iboosi jakejado agbaye lori ẹsun ifiyajẹni ati sise magomago ibo mu ki wọn se adehun lati pin ipo agbara, lẹyin ọpọlọpọ osu ti ifikunlukun to rinlẹ fi nwaye, ti ọrọ aje si ti doju de, ni wọn bura fun-un gẹgẹbi olootu ijọba losu keji ọdun 2009.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bi o tilẹ jẹ pe o n rẹrin, amọ Mugape fi ẹjẹ dudu sinu ni, to si pinnu lati mase pin ipo agbara

Tsvangirai koju ọpọ ariwisi to gbona lati orisirisi isọri awọn ọmọ ẹgbẹ oselu MDC to gba pe ipinnu rẹ lati pin ipo agbara lo mu ki Mugabe si wa lori aleefa.

O tun kuna lati tako Mugabe nidi eto isejọ̀ba to yẹ ki wọn se ni ọgbọọgba, to si ngba Mugabe laaye lati maa pasẹ, toun si n wọ tle lẹyin.

Abajade igbesẹ yi ni bi ọpọ eeyan se sọ ireti nu ninu isejọba ti Tsvangirai n lewaju rẹ, eyi to mu ki ẹgbẹ oselu MDC fidi rẹmi ninu awọn eto idibo to waye losu keje ọdun 2013.

Lẹyin osu meji pere ti Tsvangirai kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii olootu ijọba, ni Mugabe ba foju tẹnbẹlu ipo naa, to si wọgi lee patapata.

Biotilẹjẹpe Tsvangirai si wa laye lati ri ẹyin isejọba aarẹ to ti n ba jija gudu fun ọjọ pipẹ- amọ bawọn ologun se lọwọ ninu ọrọ yi lo mu ki Mugabe kọwe fipo silẹ.

Amọsa, ọpọ ọmọ orilẹede Zimbabwe ko ni gbagbe Tsvangirai gẹgẹbi akọni awọn osisẹ, ẹni to jẹ pe ijagudu rẹ fun ifẹsẹmulẹ isejọba alagbada lo mu opin de ba saa isejọba Mugabe.

Related Topics