Gani Adams gb'oriyin fun'pinlẹ Eko lori igbelarugẹ ede Yoruba

Gani Adams ati Akinwunmi Ambode

Oríṣun àwòrán, @AkinwunmiAmbode

Àkọlé àwòrán,

Gani Adams gb'oriyin fun'pinlẹ Eko

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Gani Adams ti s'apejuwe Gomina Akinwunmi Ambọde ti ipinlẹ Eko gẹgẹbi aṣaaju nipa gbigbe ede Yoruba larugẹ.

Adams nigba to n sọrọ nipa abadofin ti Gomina Ambode bu'wọlu lori gbigbe ede Yoruba larugẹ, fikun un wi pe "orilẹede tabi agbegbe ti o ba gbagbe ede rẹ, yoo gbagbe aṣa ati ise rẹ, eleyi to sọ wipe yoo pa iru agbegbe bẹẹ run.

Aarẹ ọna Kakanfo naa dupẹ lọwọ Ambọde fun ipa rẹ lori gbigbe aṣa ati iṣe Yoruba larugẹ nipa ede Yoruba.

Ti a ko ba gbagbe, Ambọde lọsẹ to kọja, bu'wọlu abadofin to f'agbara fun ede Yoruba. Eleyi to sọ ọ d'ofin fun awọn ile iwe giga ni ilu Eko lati maa gba kirẹditi ninu esi idanwo Yoruba gẹgẹ bi ọkan lara awọn kirẹditi marun ti awọn akẹẹkọ nilo lati wọ ile-iwe giga.