WHO gbe'gbesẹ lati kapa aisan Lassa

Aworan Abẹẹrẹ oogun oyinbo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn osisẹ ile-iwosan mọkanla lo ti ko aisan naa, ti mẹrin ninu wọn si ti ku

Ajọ to n risi ọrọ ilera lagbaye, WHO ti gbe igbesẹ lati kapa ajakalẹ aisan Lassa Fever to ti tan kan ipinlẹ mẹtadinlogun, to si ti pa eniyan to le ni irinwo laaarin ọsẹ marun.

Asoju ajọ naa lorilẹ Afrika, Dọkita Wondimagegnehu Alemu sọ wipe ajọ naa yoo ran awọn onimọ isegun oyinbo lati oke okun, lati wa s'akoso pipin awọn ohun eelo isegun ati sise itọsọna lori ọna lati kapa aisan naa lọna t'igbaa lode.

Alemu ni aisan naa ti tan kaakiri orilẹede Naijira atiwipe awọn ipinlẹ bii Edo, Ondo ati Ebonyi lo faragba pupọ ninu aisan naa.

Arun Iba: Naijiria gbaradi fun eto ajẹsara to pọ julọ

WHO: Ko s'anfaani ninu abẹ dida f'ọmọbinrin

Awọn osisẹ ile-iwosan mọkanla lo ti ko aisan naa, ti mẹrin ninu wọn si ti ku.

Ajọ WHO wa parọwa si ijọba orilẹede Naijiria lati sa ipa rẹ lati kapa aisan ọrẹrẹ naa, ki wọn si fi to awọn ara ilu leti nipa ṣiṣe imọtoto nigba gbogbo.

Iba ọrẹrẹ lo ti n sekupa awọn eniyan lagbegbe iwọ-oorun Afirika, ti orilẹede Benin Republic, Liberia ati Sierra Leone ti kede aisan naa lagbegbe wọn.

Ajọ WHO lo n ṣiṣẹ pẹlu awọn orilẹede yii lati jẹ ki imugbooro ko de ba ọrọ aje ati ifọwọsowọpọ lori aabo ẹnu ibode wọn.