Bola Tinubu: Ọbasanjo, IBB, ẹ lọ rọ ọ kun ni'le

Aarẹ Buhari, Bisi Akande ati Bola Asiwaju Bola Tinubu nilu Abuja Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari se ipade ẹlẹẹkeji laarin ọsẹ meji pẹlu Tinubu

Adari agba fun ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria, Asiwaju Bọla Tinubu ti parọwa si aarẹ tẹlẹri, Olusegun Obasanjo ati Ibrahim Babangida lati lọ rọ ọ kun sile bi awọn akẹgbẹ wọn to ti jẹ olori orilẹede ri .

Tinubu sọ eyi lọjọ iṣẹgun nigba to n ba awọn akọroyin ile iṣẹ ijọba apaapo sọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari.

O ni o pọn dandan ki awọn adari tẹlẹri o darapọ mọ awọn to ti ṣiṣẹ fẹyinti, ki wọn si faaye silẹ lati jẹ ki orilẹede Naijiria o ni idagbasoke.

Ninu ọrọ rẹ, asiwaju Tinubu sọ wi pe ipo tuntun ti aarẹ fi ohun si naa ni lati laja laarin gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC.

Buhari dasi ipaniyan Benue

Ọmọ ẹgbẹ APC tako Obasanjọ lori lẹta rẹ

O ni inu ohun dun pupọ si ipo asaaju naa ati wipe ohun yoo sa gbogbo ipa ohun lati mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ oselu APC ati orilẹede lapaapọ.