Igbimọ oluwadi fẹ ki wọn o da awọn oṣiṣẹ JAMB to ja'le duro

Iroyin fidirẹmulẹ pe ejo ajoji kan mi miliọnu mẹrindinlogoji naira lọọfisi ajọ JAMB
Àkọlé àwòrán,

Iroyin fidirẹmulẹ pe ejo ajoji kan mi miliọnu mẹrindinlogoji naira lọọfisi ajọ JAMB

Igbimọ oluwadi ti wọn gbekalẹ lati tọ pinpin obitibiti owo to poora l'ọọfisi ajọ JAMB ti d'aba wipe ki wọn o da awọn ti aje iwa naa ṣi mọ lori duro lẹnu iṣẹ.

Agbẹnusọ fun JAMB, Fabian Benjamen sọ fun BBC Yoruba pe igbimọ naa ti pari iwadi rẹ, o si ti gbe abọ iwadi naa lọ si iwaju minisita fun eto ẹkọ ni Naijiria fun ayẹwo.

O ni, "ti minisita ba fi bu ọwọ lu awọn aba naa, ajọ JAMB yoo da a awọn oṣiṣẹ rẹ ọhun duro lẹnu iṣẹ, lẹyin eyi ti wọn yoo fa wọn le awọn agbofinro lọwọ fun igbesẹ to ba yẹ lori ọrọ wọn."

O ni bi o tilẹ jẹ wipe iroyin nipa oṣiṣẹ ajọ naa, Philomena Chieshe to sọ fun igbimọ oluwadi pe ejo airi kan lo deede wọ inu ọọfisi oun, to si gbe miliọnu mẹrindinlogoji mi lo jade sita, Benjamen ni awọn meje ni wọn ṣe magomago owo ti ajọ naa pa wọle lati ara awọn kaadi ti o ta fun awọn akẹkọọ saaju ki wọn o to dawọ tita kaadi naa duro.