Ọmọ tuntun gba ominira lẹyin ti wọn san owo itọju rẹ ni Gabon

Angel
Àkọlé àwòrán Ọmọ tuntun, Angel lo oṣu maarun akọkọ aye rẹ nileewosan

Idunnu ṣubu l'ayọ fun iyalọmọ kan nigba ti ileewosan aladani kan ni Gabon yọnda ọmọ tuntun rẹ fun, lẹyin ti wọn ti gba ọmọ naa silẹ fun ọpọlọpọ oṣu nitori wipe awọn obi rẹ ko ri owo itọju san.

Iya Angel sọ fun BBC pe omi ọyan ohun ti gbẹ lẹyin ti wọn pin oun niya pẹlu ọmọ naa fun oṣu maarun akọkọ aye rẹ.

Iṣẹlẹ ohun jẹ iyalẹnu fun awọn eniyan l'orileede naa, iranlọwọ si dide fun un lati ọdọ awọn ara ilu.

Owo itọju naa to jẹ ẹgbẹrun mẹta le ojilelẹgbẹta dọla di sisan lẹyin eto ipolongo to waye fun idile naa.

Aarẹ Ali Bongo naa wa lara awọn to da owo fun wọn.

Akọroyin BBC nilu Libreville, to jẹ olu-ilu Gabon, Charles Stephan Mavoungou jabọ iroyin pe, wọn fi panpẹ ofin mu oludari ileewosan naa l'ọjọ aje, wọn si fi ẹsun jiji ọmọ ikoko naa gbe kan an, bi o tilẹ jẹ wipe wọn pada fi oju fo ẹsun naa.

Ọsẹ yii ni wọn yọnda Angel lati kuro ni ileewosan ọhun to n bẹ lapa ariwa ilu Libreville.

Iya ọmọ naa, Sonia Okome, sọ fun BBC bi inu rẹ ṣe dun to, ṣugbọn o salaye pe ibanujẹ ati ayọ ni iṣẹlẹ naa jẹ fun oun:

"Inu mi i dun lati gba ọmọ mi pada. Ṣugbọn, mo tọrọ aforiji pe mi o ni le fun l'ọyan nitori wipe omi ọyan mi ti gbẹ lẹyin oṣu maarun."

O tun fi aidunnu rẹ han lori bi ọmọ naa ko ṣe ti i gba abẹrẹ ajẹsara kankan.

Owo ileewosan naa lo jẹ owo iye ọjọ ti ọmọ naa lo ninu ẹrọ ti wọn fi n tọju awọn t'oṣu wọn o pe si nitori wipe ọjọ ibi rẹ ko ti to o ti iya rẹ fi bi.