Naijiria: Igbakeji aarẹ fẹ s‘eyawo ọmọ rẹ

Oluwadamilola Osinbajo ati ọkọ afesona re Oluseun Bakare Image copyright Yemi Osinbajo/Facebook
Àkọlé àwòrán Agogo ifẹ lu nile igbakeji aarẹ Ọsinbajo ni ayajọ ololufẹ

Awọn ọmọ Naijiria ji lowuro ọjọ ayajo ololufe lati salabapade ikede ayọ ati idunnu ti igbakeji aarẹ orilẹẹde yi, ọjọgbọn Yemi Ọsinbajo fi sọwọ nipa igbẹyawo ọmọ re, Oludamilọla to'n bọ lọna.

Lori facebook,Instagram ati twitter, ko fẹ si ibi ti ikede naa o si.

Ikede naa ko so ọjọ ti igbeyawo naa yoo waye sugbọn ọpọ ẹniyan lo ti ki igbakeji Aarẹ ku orire isopo naa.

Oluseun Bakare ni orukọ ọkọ afesọna ọmọ igbakeji Aarẹ, Oluwadamilọla.

Ọpọ ẹniyan lo'n bere nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara.

Ibeere wọn pẹka lori ẹsin rẹ ati ọmọ ẹni ti o jẹ.

Iroyin naa ko ti daju sugbọn oun ti ko ruju ni wipẹ,alagba Osinbajo ti kede igbeyawo ni ti e.

Oku ẹni ti wọn yoo fi iwe pe lo si ibi ayẹyẹ naa.

Related Topics