Akanṣe iṣẹ ogun Operation Cat Race bẹrẹ loni

Ikọ ọmọ ogun orilẹede Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Akanṣe iṣẹ ogun Operation Cat Race bẹrẹ loni

Ikọ ọmọ ogun orilẹede Naijiria ti bẹrẹ akanṣe eto abo ti wọn pe ni Operation 'Cat Race' lati dena ipinija ọrọ abo ni awọn agbegbe aala ipinlẹ Benue, Taraba, Nasarawa, Niger ati Kaduna ni ọjọọbọ.

Agbẹnusọ fun ileesẹ ọmọogun, Sanni Kukasheka Usman sọ fun BBC pe iṣẹ naa ti bẹrẹ ni pẹrẹwu ni ọjọọbọ ti yoo si waye titi di ọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹta ọdun yii.

Ikọ ọmọ ogun orilẹede Naijiria ṣe akanṣe eto abo "Ayem Akpatuma", eyi ti o tumọ si "Operation Cat Race" ni ẹnu aala ati awọn agbegbe ipinlẹ Benue ati awọn ipinlẹ miiran ni apa ariwa orilẹede Naijiria lati mu opin ba ijamba, ikọlu ati ija laarin awọn darandaran fulani ati awọn agbẹ afokoṣọrọ ni awọn ipinle wọnyi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orisirisi ise akanse bayi ni iko omo ogun orileede yii maa nse loorekoore

Agbẹnusọ fun awọn ologun sọ pe awọn eleto ileeṣẹ aabo gbogbo miiran yoo ṣiṣẹ pẹlu awọn ọmọ-ogun Naijiria ninu iṣẹ akanṣe yi lati dẹkun iwa igbesunmọmi, idunkookomọni, ipaniyan, iwa janduku ati awọn iwa ipanle miiran.

Gomina Ortom k'igbe fun iranlọwọ

Nibayi, Gomina Ipinlẹ Benue, Samuel Ortom ti k'igbe pe ajọ iṣọkan orilẹede agbaye (United Nations) lati dasi eto idaabobo awọn ara ipinlẹ Benue latari idaamu ati ipaniyan ti o wa n ye lọwọ awọn darandaran fulani ni ipinle naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Samuel Ortom ati Ibrahim Idris wọ sokoto kan naa bayi

Gomina Ortom pe ipe yii nilu Abuja ni ọjọọru nigbati o se abẹwo si ile iṣẹ ajo iṣọkan agbaye fun idagbasoke (UNDP) lati ṣe atotonu lori ohun ti o pe ni piparun awọn eniyan ni ipinlẹ Benue.

Ìjọba Nàijíríà yòó lo àwọn ológun nì Benue

Ọmọogun ko eniyan mọkanla s'ihamọ

Agbẹnusọ fun gomina naa, ọgbẹni Tever Akase sọ fun BBC pe ipe ti Gomina Ortom pe di dandan latari bi ijọba apapọ ṣe kọ eti ikun si ẹbẹ lati daabo bo ipinlẹ naa lọwọ awọn darandaran fulani.

Ortom ti wọ sokoto kan naa pẹlu ọga awọn olopa lorilẹede yi Ibrahim Idris lori awọn ipenija aabo nipinlẹ Benue, ti o si pe fun ikọwe fiposilẹ rẹ pẹlu.

Awọn olugbe Agbegbe

Awọn eniyan ti ipinlẹ Benue ti fi ero ọkan wọn si isẹ ti awọn ọmọ-ogun bẹrẹ loni.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ ti n sa asala fun ẹmi wọn

Olugbe kan ni ijọba ibilẹ Guma ni Ipinlẹ Benue, Gideoni Nyom sọ fun BBC pe kii awọn ologun gbọdọ ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn eniyan agbegbe ati awọn ipinlẹ yi ki wọn too le ri aṣeyori kankan ṣe.. O sọ pe awọn eniyan ti wa ninu ibẹru pẹlu ogunlọgọ awọn ọmọ-ogun to ṣe ifihan nibi ibẹrẹ iṣẹ naa.

Nyom sọ pe abule kan ni Guma kagbako inọ nigbati awọn apaniyan danọ sii.