NAPTIP: Babalawo to n fọmọ sowo lugbadi ofin

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán ọgọọrọ awọn ọmọ ati iya, lọti bo sowo awon ọdaran ti wọn n fi ọmọ kekeeke sòwò

Ajọ to n gbogun tiwa ifinisowoeru lorilẹede Naijiria, NAPTIP ti fi panpẹ ofin mu onisegun ibilẹ kan to n ta awọn ọmọ kekeeke.

Iroyin naa ni awọn obinrin miran ti ko rọmọ bi, n gba ọna ẹburu lati bimọ, eleyi to n mu wọn lọsi ọdọ Babalawo ti yoo pese ọmọ fun wọn.

Owo tita ọmọ kekeke ti bẹrẹ sini jẹ òwò ti n mu ogunlọgo miliọnu wọle fawọn to n sowo naa.

Ajọ NAPTIP naa ti wa sọ agadagodo sẹnu ọna ayederu ile -iwosan agbẹbi ti ọmọkunrin naa n lo, bii ile ifọmọsowo l'Abuja.

Agbenusọ fun ajọ naa, Josiah Emerole nigba to n ba BBC sọrọ wipe, iwadi ajọ naa bẹrẹ losu meji sẹhin, lẹyin ti ọwọ sinkun ọlọpa mu obinrin kan ti wọn fẹsun kan wipe o ji ọmọ ọse kan gbe, lati ilu Abuja lọ sipinlẹ Niger, lorilẹede Naijiria.

Emerole fikun wipe, iwadi obinrin naa lo jẹ kawọn ri onisegun ibile naa gbamu, tawọn si ri onde, agbo lorisirisi ati erọja ibilẹ ti wọn n lọ nibi ile-iwosan ayederu naa, lati jẹ ko dabi ẹniipe awọn obinrin yi ti loyun amọ ti kọsi si oyun ninu wọn.

Emerole ni obinrin tawon ọlọpa gbamu naa ko ni pẹ foju bale ẹjọ, ati wipe awọn to ma n tọju awọn ọmọ ti ko ni obi, ti bẹrẹ sini fun ọmọ ti wọn jigbe naa ni itọju.

Ti a ko ba gbagbe, o ti to ọdun kan tawọn ajọ eleto aabo lorilẹede Naijiria ti gba ọgọọrọ awọn ọmọ ati iya, lọwọ awọn ọdaran ti wọn n ta awọn ọmọ kekeke lati fi sowo.