Olootu ijọba Ethiopia kọwe fipo silẹ

Hailemariam Desalegn Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ikọwe fiposilẹ Olootu ijọba Ethiopia lo n waye laarin rogbodiyan to gba orilẹede naa kan

Awọn ileesẹ iroyin to wa lorillẹede Ethiopia ti n fi iroyin ransẹ pe olootu ijoba orilẹede naa ti kọwe fipo rẹ silẹ.

Bakanaa la gbọ pe Hailemaria Desalegn tun kọwe fipo rẹ silẹ gẹgẹbi alaga igbimọ oludari fẹgbẹ oselu Peoples Democratic Front.

Wọn ko tii salaye idi kankan to fi se bẹẹ.

Sugbọn isẹlẹ ikọwe fipo silẹ rẹ naa lo n waye laarin ifẹhonu han lati tako ijọba orilẹede naa lawọn ilu to tobi julọ nibẹ tii se Oromia ati Amhara.

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn eeyan lo ti jalaisi, nigbati wọn sọ ogunlọgọ mii si ahamọ lati bii ọdun mẹta ti eto ifẹhonu han lati tako isejọba orilẹede naa ti nwaye.

Ijọba orilẹede Ethiopia ti tu ẹgbẹlẹgbẹ awọn alatilẹyin ẹgbẹ alatako silẹ ni ahamọ

Bakanaa ni iyapa n waye laarin ẹgbẹ to n sejọba lori ọna ti wọn yoo gba lati koju aifararọ ọhun.

Ninu akọtun rogbodiyan mii to tun waye, eeyan mẹwa lo gbẹmi mi, ti ẹgbẹlẹgbẹ mii si fara gbọgbẹ lasiko iwọde kan.

Àkọlé àwòrán Ọpọlọpọ awọn eeyan lo ti gbẹmi mi laipẹyi lasiko iwọde kan to lọwọ rogbodiyan ninu lagbegbe Amhara

Cyril Ramaphosa di aarẹ South Africa

Cyril Ramaphosa, aarẹ tuntun fun orilẹede South Africa?

Akọroyin BBC, Emmanuel Igunza to wa ni olu ilu orilẹede Ethiopia, Addis Ababa ni, ijọba ti tu omilẹgbẹ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oselu alatako silẹ ni ahamọ lati ọsẹ diẹ si asiko yi,

amọ sibẹsibẹ, ifẹhonu han naa si n tẹsiwaju.

Oniruuru isẹlẹ ifẹhonu han lo nwaye lemọlemọ lorilẹede Ethiopia latọdun 2015, tawọn oluwọde si n beere fun atunto ọrọ aje ati eto oselu, to fi mọ fifi opin si iwa ijẹkujẹ.

Wayi o, Getaneh Balcha, tii se igbakeji alaga ẹgbẹ oselu alatako ti fesi si isẹlẹ bi olootu ijba orilẹede naa se kọwe fipo silẹ.

Balcha ni " Ifẹhonu han ati iwọde awọn araalu lo mu ko kọwe fipo silẹ. Ibẹrẹ lasan ni eleyi, wọn sẹsẹ nmu ẹyẹ bọ lapo ni, nitori gbogbo awọn eeyan to wa ni ẹka alasẹ ni wọn yoo papa gbe igbesẹ yi, ti wọn yoo si gbe ijọba kalẹ fawọn araalu. Iroyin ayọ nla ni eleyi lati orilẹede Ethiopia. Awọn eeyan si gbọdọ tẹsiwaju ninu ijagudu yi ni."

Contact BBC News Yoruba---- Ẹ kàn sí ojú òpó ìròyìn BBC Yorùbá

Send your complaint to BBC Yoruba------ Ẹ fi ẹ̀dùn ọkàn yín ránsẹ́ si BBC Yoruba

Related Topics