Cyril Ramaphosa di aarẹ South Africa

Cyril Ramaphosa Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Cyril Ramaphosa ni igbake aarẹ fun Jacob Zuma

Cyril Ramaphosa ti di aarẹ South Africa lẹyin ti olori orileede naa, ti wahala d'oju kọ, kọwe fiposilẹ.

Aarẹ tuntun naa nkan ni oludije ti wọn fi orukọ rẹ silẹ n'ile igbimọ aṣofin lọjọbọ.

Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣelu ANC ti ṣọ fun ọgbẹni Zuma pe ko kuro lori aga iṣakoso tabi ko fi oju wina ki wọn o d'ibo ta ko o.

Ninu ọrọ kan to ṣọ lori ẹrọ mohunmaworan, Zuma ni oun n fipo silẹ lọgan, ṣugbọn o tun sọ wipe oun ko fi ara mọ igbesẹ ẹgbẹ oṣelu naa.

Awọn ẹsun iwa ijẹkujẹ lọlọkan o jọkan ni wọn fi kan ọgbẹni Zuma, ṣugbọn o ni oun ko jẹbi ẹsun hihu iwa kebekebe kankan.

Ẹgbẹ alatako kan, Economic Freedom Fighters, fi awọn t'oku si ori ijoko nibi ipade ijiroro ile igbimọ aṣofin naa.

Ẹgbẹ naa n'ifẹ si eto idibo tuntun, ju ki ẹgbẹ ANC o yan aarẹ tuntun