Ebun f'ẹni ba ri Shekau: Miliọnu mẹta naira ni

Abubakar shekau, asiwaju ikọ Boko Haram

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ igba lawọn ologun nkede pe Abubakar Shekau ti jade laye

Ileeṣẹ ologun orileede Naijiria ti kede ẹbun miliọnu mẹta naira fun ẹnikẹni to ba ni iroyin tabi ifitonileti kankan to le seranlọwọ lati ri olori igun kan ninu ẹgbẹ Boko Haram, Abubakar Shekau ti wọn n wa.

Wọn fi ikede naa sita loju opo ẹrọ ayelujara Twitter ileesẹ ologun lọjọbọ.

Ṣaaju, lọjọ kẹtala, oṣu keji ni wọn fi ikede sita wipe Shekau ti sa kuro ninu igbo Sambisa nitori wipe awọn ologun nfinna mọ-ọ

Ati wipe, o tun fi ijaabu boju bi obinrin.