Eku sé oko ìrẹ́si lọsẹ́ ni Kebbi

Eku sẹ oko irẹsi l'ọsẹ ni Kebbi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn eku naa n ya wọ awọn oko irẹsi ni ipinlẹ Kebbi

Awọn alasẹ ni ipinlẹ Kebbi to wa ni iwo-orun ariwa Naijiria sọ wipe awọn ofan ati kokoro ya wọ inu awọn oko irẹsi ti wọn si ba awọn nkan ọgbin jẹ

Iroyin fi han wipe ajalu yii ti bẹrẹ si s'okunfa ifi ise agbe silẹ laarin awọn ti ajalu naa ba.

Awọn onwoye nfoya wipe isẹlẹ yii le je ki irẹsi ti wọn gbin ni Naijiria ko wọn nitori osẹ t'awọn eku ati kokoro nse ninu ogunlogo oko to wa ni ipinlẹ Kebbi, to jẹ okan lara awọn ipinlẹ ti wọn tin gbin irẹsi ju lọ.

Ijọba apapọ Naijiria fẹ fi ofin de gbigbe irẹsi wole lati ilẹ okere ninu ọdun 2018 nitori ati ran awọn agbẹ Naijiria l'ọwọ .

Iroyin fi han wipe isẹlẹ naa le pupọ ninu ijọba ibilẹ Augie, Argungu, Bagudo, Dandi, Kalgo, Bunza ati Suru.

Agbe kan ti isẹlẹ naa kan nilu Argungu, Sanusi Adamu, sọ fun BBC wipe bo tilẹ jẹ wipe ọrọ naa bẹrẹ lati nkan bi osu diẹ sẹyin, o buru pupọ l'asiko yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Kebbi jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ to jẹ ara waju nibi gbigbin irẹsi ni Naijiria

Sanusi sọ wipe: "Awọn eku naa pẹlu awọn kokoro ba oko ọpọ ninu awọn agbe Argungu jẹ." .

O s'afikun wipe awọn agbe ti din gbigbin irẹsi ku nitori ikolu awọn eku ati kokoro naa.

Sugbọn igbimọ ton s'akoso nkan ọgbin ni pinlẹ Kebbi sọ wipe oun ti gbe igbese to tọ lori awọn eku ati kokoro naa.

Komisana isẹ agbẹ ni ipinlẹ naa, Alhaji Garba Dan dika, sọ wipe lati igba ti iroyin naa ti tẹ wọn l'ọwọ lati ọsẹ meji sẹyin ni wọn ti s'alaye isoro naa fun ijọba ipinlẹ naa.

Komisanan naa sọ wipe ipinlẹ naa ti ra ogun eku ati ti kokoro ti wọn yoo fin lati okere nitori ati gb'ogun ti awọn nkan ti wọn yo awọn oko naa lẹnu.