Buhari ṣ'eto igbimọ fun abẹwo awọn ipinlẹ ti o ni ikọlu

Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu awọn adari nilu Abuja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ ti bu ẹnu lu iha ti ijọba kọ si awọn ikọlu darandaran jakejado Naijiria

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣ'eto igbimọ miiran ti yoo lọ ṣe abẹwo si gbogbo awọn agbegbe ti o ni ikọlu nipasẹ ija laaarin awọn agbẹ ati darandaran fulani ni orilẹ-ede Naijiria.

Abẹwo naa, gẹgẹbi Gomina Mohammed Abubakar ti ipinlẹ Bauchi ṣe sọ, yoo jẹ ki ijọba wa wọrọkọ fi ṣ'ada lori awọn ọna ati "ṣe atunṣe ati dẹkun irora awọn eniyan ni awọn agbegbe naa".

Ọgbẹni Abubakar, ti o ba awọn oniroyin sọrọ nilu Abuja lẹyin ipade igbimọ ti o ga julọ lori eto ọrọ aje orilẹede (NEC) sọ wipe igbakeji aarẹ, ọjọgbọn Yemi Osinbajo ni yoo jẹ adari igbimọ naa.

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Àkọlé àwòrán,

Ipinlẹ Benue ni iṣẹlẹ ipaniyan darandaran ni osu kini ọdun 2018

O sọ pe igbimọ Osinbajo ti Aarẹ Buhari ti gbe kalẹ ni yoo jẹ afikun si igbimọ alakoso ti o ṣaju rẹ tẹlẹ, eyi ti Gomina ti Ebonyi, David Umahi n ṣ'akoso rẹ.

O sọ siwaju sii wipe Ọjọgbọn Osinbajo ti ṣe agbekalẹ ipinnu ati ijabọ fun igbimọ ti o ga julọ lori eto ọrọ aje orilẹede (NEC) nibi it gbogbo awọn gomina ipinlẹ ati awọn minisita peju-pesẹ si.