Hungbo: Kikọlu awọn ọmọ Naijria ko lee dinku labẹ Ramaphosa

Eefin sọ awọn eero si nsare kaakiri loju opopona kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Isẹlẹ kikọlu awọn ajeji ti di ohun to n waye lemọlemọ ni orilẹede South Africa

Kii se ariwo kekere lo sọ lagbaye nigba ti Ọgbẹni Jacob Zuma kọwe fi ipo rẹ silẹ ti Cyril Ramaphosa si gba ipo rẹ.

Nibayii, awọn ọmọ orilẹede Nigeria ti n sọrọ lori afojusun wọn lori ayipada isejọba yii.

Jendele Hungbo, ọmọ orilẹede Naijiria kan to n gbe lagbegbe Mafikeng to ba BBC Yoruba sọrọ ni ko si afojusun kan ti awọn ọmọorilẹede Naijiria to n gbe ni orilẹede South Africa ni ju wipe wọn n se agbeyẹwo ijọba orilẹede South Africa ati ti Naijiria ni ifẹgbẹkẹgbẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipenija nla n bẹ niwaju fun aarẹ tuntun ni South Africa, Cyril Ramaphosa

"Lootọ isejọba yii pada sugbọn ohun ti awa gẹgẹbii ọmọ Naijiria ngbe yẹwo lori ọrọ yii ko ji afiwe ijọba orilẹede tiwa ni Naijiria ati ti South Africa ti a n gbe. Paapaajulọ lori awọn nkan bii ilana isejọba, idagbasoke ọrọ aje, ati igbayegbadun ọtun fun awọn ajeji to n gbe nibẹ."

Ohun kan ti awọn eniyan yoo fẹ mọ nipa ayipada yoowu to lee de eto isejọba ni orilẹede South Africa ni wahala ati ikọlu awọn ọmọ orilẹede ti kii se ọmọ orilẹede South Africa.

Ọpọ igba ni wahala yii ti waye ninu eyi ti awọn ọmọ orilẹede South Africa yoo maa kọlu awọn ọmọ ilẹ okeere to n gbe nibẹ ti wọn yoo si ba dukia wọn jẹ.

Isẹlẹ kikọlu awọn ajeji ti di ohun to n waye lemọlemọ ni orilẹede South Africa paapaa julọ laaring ọdun mẹsan sẹyin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lara awọn orilẹede ti ọmọ Naijiria pọ si julọ ni South Africa

Amọsa, Ọgbẹni Jendele Hungbo ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria to wa ni orilẹede South Africa ko ni igbagbọ wipe ikọlu awọn ajeji yoo dinku lasiko isejọba Cyril Ramaphosa.

Lori ọrọ yii ohun to jaju nipe, se ijọba yoo gbe ajọ tabi ileesẹ silẹ lati dide si ọrọ yii. Sugbọn ni tiwa, ko si ireti pe yoo dinku.

Saaju ko to kan isejọba yii ni ikọlu awọn ajeji ti bẹrẹ ni orilẹede South Africa ko si lee duro lori rẹ bi a se n woo yii."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ajeji ni wọn ti fara kaasa ni orilẹede South Africa

Bakanna lo salaye wipe, pẹlu bi nkan se n lọ yii, afaimọ ki awo ẹgbẹ oselu ANC to n se ijọba ni orilẹede naa o maa sun lebi bi wọn ko ba tete fi ori ikoko sọọdun lori atunto to lee fun ẹgbẹ oselu naa lẹnu ọrọ ni ọdun 2019 ti ibo apapọ miran yoo waye.

O ni "alaafo ni wọn fi isejọba Ramaphosa di titi di igba ti ẹgbẹ oselu naa yoo fi ri ojutu si atunto to n gbero lori awọn afojusun rẹ gbogbo.