Ole aji maluu pa eeyan marundinlogoji ni Zamfara

oku maluu kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọpọlọpọ ẹmi ati maluu ni awọn ọdaran agbebọn naa ti pa kaakiri ipinlẹ Zamfara ati awọn ipinlẹ miran.

Ko din ni eniyan marundinlogoji ti awọn eeyan kan ti wọn funrasi pe wọn jọ agbebọn ti ṣe ikupa ni ipinlẹ Zamfara ni apa iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Iroyin sọ wi pe awọn agbebọn naa ti wọn jẹ ole agbe-maluu, gun alupupu ṣigun kọlu ileto naa ti wọn si ṣi ina ibọn bolẹ, bẹẹni wọn n ti ina bọ ile gbogbo nibẹ.

Gẹgẹ aabọ iroyin akọroyin BBC, Chris Ewokor, nilu Abuja, ọpọlọpọ eniyan lo f'ara ṣeṣe ninu isẹlẹ naa.

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ileto ati ilu lo ti wa ninu ibẹrubojo nitori ikọlu awọn ole ajimaluu ni orilẹede Naijiria

Eyi kun omilẹngbẹ awọn iṣẹlẹ ikọlu awọn ileto kekeeke to ti waye sẹyin ni ipinlẹ Zamfara ninu eyi ti ọpọlọpọ mi ti sọnu latọwọ awọn ole aji maluu.

Ni alẹ patapata ni ikọlu yii waye ni ileto Birane ni agbegbe ijọba ibilẹ Zurmi.

Awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Zamfara ko lee sọ ni pato iye awọn to fi ara kaaṣa ikọlu yii sugbọn awọn to se oju wọn ni sa dede lawọn ole aji maluu naa dabo ọkọ ọhun to n ko awọn oniṣowo lọ si ọja abule ti wọn n lọ. Wọn ge ọrun awakọ ọkọ naa ki wọn to bẹrẹ si ni yinbọn fun gbogbo awọn to wa ninu ọkọ naa lai ṣẹ ẹyọ ẹmi kan ku, lẹyin eyi ni wọn wa da ina sun ọkọ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ikọlu awọn ole aji maluu ti n di tọrọ fọnkale ni ipinlẹ Zamfara.

Bi wọn se se eyi tan ni awọn agbebọn yii tun gba ọja abule naa lọ nibi ti wọn tun ti da ina ibọn bolẹ.

Awọn agbebọn yii tun pa ọkunrin kan to n wa alupupu fi isẹ aje to gbe arabinrin kan ati awọn ọmọ rẹ mẹta ti awọn eeyan si n wa kiri bayii.

Gomina Yari ti ipinlẹ̀ Zamfara koro oju si isẹlẹ ikọlu naa.

Nibayii, gomina ipinlẹ Zamfara Alhaji Abdulaziz Yari Abubakar ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ati ipaniyan ọhun pẹlu asẹ fun awọn agbofinro ni ipinlẹ naa lati se awari awọn apaniyan naa.

Gomina Yari ni owo nla ni ipinlẹ Zamfara n na si ọrọ abo eleyi to ni o nmu ifasẹyin ba idagbasoke ba ipinlẹ naa pẹlu bi ko se si owo pupọ mọ lẹyin ti wọn ba ti yọ owo fun aabo, lati na fun awọn isẹ idagbasoke miran ni ipinlẹ ọhun.

Ikọlu awọn ole aji maluu ti n di tọrọ fọnkale ni ipinlẹ Zamfara.

Ni osu kọkanla ọdun 2017 eeyan mẹrinlelogun ni wọn se iku pa ti wọn si tun da ina sun awọn ile lasiko ti awọn ole aji maluu yii kọlu ileto mẹta ni ipinlẹ Zamfara yii kan naa.