TSAIGUMI, ọmọ tuntun ileesẹ ọmọogun ofurufu Naijiria

Baluu adanikan fo ti ileesẹ ọmọogun ofurufu orilẹede Naijiria ti wọn da orukọ rẹ pe ni Tsaigumi

Oríṣun àwòrán, @NigAirForce

Àkọlé àwòrán,

TSAIGUMI, idagbasoke ọtun ni ẹka ijagun ofurufu ni Naijiria

Ni ọjọọbọ ọjọ kẹẹdogun osu keji ọdun 2018 ni aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari si asọ loju baluu adanikan fo ti ileesẹ ọmọogun ofurufu orilẹede Naijiria ti wọn da orukọ rẹ pe ni Tsaigumi.

Kini awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Ohun ti o ko mọ nipa baluu adanikan fo ti ileesẹ ọmọogun ofurufu orilẹede Naijiria sẹsẹ se yii.

  • Baluu yii lee da fo funrarẹ lai jẹ wipe awakọ baluu wọ inu rẹ.
  • Tsaigumi ni baluu adanikan fo akọkọ ti ileesẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria yoo da se fun ara rẹ.
  • O wa fun jija ogun ofurufu.
  • Baluu adanikan fo Tsaigumi lee ri ohun to n sẹlẹ ni oke ilẹ ketekete lati inu ofurufu wa pẹlu ẹrọ iyaworan ti wọn pe orukọ rẹ ni 'infra-red camera system'
  • Yatọ si fun jija ogun ofurufu, Tsaigumi tun wa fun sisẹ isẹ ọlọpaa, asiko ijamba tabi isẹlẹ pajawiri pẹlu sise eto abo fun awọn leekanleekan, sise amojuto agbegbe ori omi ati awọn ọpa epo to fi mọ didaabo bo aala ati ibode gbogbo.
  • Bakanna ni Tsaigumi wulo fun wiwa awọn to ba sọnu ati didoola ẹmi.
  • Gẹgẹbi ọrọ ọgagun agba ileesẹ ọmọogun ofurufu lorilẹede Naijiria se sọ, baluu adanikan foyii le da sisẹ ni ssan ati oru.
  • baluu adanikan fo ti ileesẹ ọmọogun ofurufu Naijiria sẹsẹ se naa lee sisẹ kọja wakati mẹwa lai duro ti yoo si fo si iwọn bata ẹgbẹrun marundinlogun so.

Oríṣun àwòrán, @NigAirForce

Àkọlé àwòrán,

Tsaigumi yoo wulo fun gbigbogun ti ikọ̀ adukukulaja Boko Haram

Ju gbogbo rẹ lọ, baluu adanikan fo ti ileesẹ ọmọogun ofurufu orilẹede Naijiria sẹsẹ se ti wọn da orukọ rẹ pe ni Tsaigumi yii le e ko ipa pataki ninu eto idaabo bo ẹmi ati dukia gbogbo ti ijọba apapọ n se ni pataki julọ lagbegbe ila oorun ariwa orilẹede Naijiria nibi ti awọn ikọ adukukulaja ni, Boko Haram ti n sọsẹ.