Banki agbaye se ẹyawo milionu 486 fun ina ọba ni Naijiria

Ina ọba ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipenija nla ni aisina ọba ni orilẹẹde Naijiria

Banki agbaye ti kede ibuwọlu ẹyawo milliọnu ọrinlẹniwo ati mẹfa fun agbega ipese ina ọba ni orilẹede Naijiria.

Wọn sọ wipẹ ''idokowo naa labẹ isẹ akanse pipin ina ọba jakejado orilẹẹde naijiria yoo mu ilọsiwaju ba pipin ina ọba ti yoo si je ki awọn ile ise to'n pin ina ọba maa le fina sọwọ si awọn onibara wọn deede.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ẹrọ amunawa lọpo a ma lo lati pese ina.

Awọn onimọ ijinle a ma saba di ẹbi aisidagba soke ni Naijiria ru bi ẹka ina ọba ti se dẹnu kole lorilẹẹde Naijiria.

Aisi ina ọba sokunfa bi ọpọ ẹniyan ti se'n na ọwọ to po lori rira ẹpo si ẹrọ amunawa lọpo igba.