Rogbodiyan NURTW: Ọlọpa gbe Ọlorunwa satimọle

ikọ ọlọpa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọlọpa sọ pe afurasi yii jẹwọ pe oun gba ẹ̀gbẹ̀rún lọna ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta naira lati ṣe iṣẹ ibi naa

Afurasi apaniyan kan ti orukọ rẹ njẹ Adeola Williams, ti inagijẹ rẹ n jẹ "Ade Lawyer", ti lu panpẹ ijọba ti o si ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa ti ẹka ọga agba ọlọpaa orilẹede yii.

Afurasi naa ni ọlọpaa ni idaniloju pe o lọwọ ninu iku ọmọ ẹgbẹ awakọ lorilẹede Naijiria, NURTW, Ganiyu Ayinla, ti inagijẹ rẹ n jẹ Piero ni agbegbe Obalende n'ilu Eko ni ọjọ kẹtalelogun osu kini ọdun 2018.

Ọwọ ṣikun awọn ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ tẹ "Ade Lawyer" nilu Akure lọjọbọ.

Gẹgẹbi awọn ọlọpa ti se e lalaye, Ade Lawyer ti wa ninu awọn ti ọlọpaa nwa lati bii ọdun marun sẹyin latari ipa rẹ ninu awọn ipaniyan oriṣiriṣi ni awọn ipinlẹ to wa ni ẹkun iwọ-oorun guusu orilẹede Naijiria.

Ọwọ palaba oludari NURTW tẹlẹri kan, Rafiu Akanni ti wọn npe ni Ọlọrunwa naa se'gi pẹlu.

Ọlọrunwa ni ẹni ti ọlọpaa sọ wipe idaniloju wa pe o gbe iṣẹ ipaniyan fun "Ade Lawyer" lati pa alabadupo rẹ, ti wọn pe ni Azeez Lawal.

Ọlọpa sọ pe afurasi yii jẹwọ pe oun gba ẹ̀gbẹ̀rún lọna ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta naira lati ṣe iṣẹ ibi naa. Ṣugbọn, o padanu afojusun rẹ, eyi ti o ṣe iku pa oluranlọwọ ti Lawal, Ayinla.

Awọn ọlọpa sọ pe ori lo ko Lawal yọ ninu iṣẹlẹ ipaniyan yii ti o si gbọ'gbẹ pẹlu ọgbẹ ibọn.

"Adeola jẹwọ pe Ọgbẹni Ọlọhunwa ti n pe oun lati iṣọra daradara nibi ti o farapamọ si ati pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn ọmọ ẹyin oun.

"O tun darukọ ọpọlọpọ awọn eniyan miran ti o ti yin'bọn pa bii Hamburger, alaga kan ni ẹgbẹ awakọ ni Oshodi, Babajide Dosumu ti wọn n pe ni Mados ni Ebute Meta, Salawe ni Ajah, Ganiyu Asaro ati awọn mẹrin miiran ni agbegbe Badore nibiti o sọ pe oun rọ'jo ọtan ibọn sinu ọkọ wọn ti oun fi pa awọn eniyan maraaarun ti o wa ninu ọkọ naa.

Wọn mu Ọlọrunwa ni Ebute Meta nilu Eko.