Ọdọmọde to n seranwọ fun awọn ọmọ ita ni Calabar

Okina ati awọn ọmọ ti o ran lọwọ Image copyright STREET PRIESTS
Àkọlé àwòrán Pupọ ninu awọn ọmọ̀ ti Okina ran lọwọ lo wa lati ibudo awọn ogunlende

Ninu ọpọlọpọ lẹta ti a maa n ri i gba lati ọdọ awọn oniroyin ni ilẹ Afirika, onkọwe Adaobi Tricia Nwaubani ṣe agbeyẹwo bi ọdọmọkunrin kan ṣe n tun aye awọn ọmọde to n gbe lawọn ojupopo.

James Okina ko fi nkan kan pamọ ninu gbogbo awọn iwa kebe-kebe to wu nigb to wa ni ọdọ langba: Afọwọra, mimu dukia awọn akkkọ akẹgbẹ rẹ to fi mọ sisa kuro n'ile.

O jẹwọ, o ni, "Mo n darapọ mọ ẹgbẹ buburu."

Ijẹwọ rẹ naa jẹ eyi to yani lẹnu pupọ, paapa julọ, ti enyan ba mọ wipe Okina, to si jẹ ọdọ langba ti n ṣe oludari ajọ alaanu to n ran awọn ogunlọgọ awọn ọmọ to fi awọn oju opopona se ile jakejado ilu Calabar, ti se olu ilu Cross Rivers, llkun guusu guusu Naijiria lọwọ.

O gboriyin ayipada rẹ yi fun eniyan meji: ibatan rẹ kan, ati ọmọ ọdun mẹtala alakisa kan to pade nibi idije ere bọọlu alafẹsẹgba kan llyin to pari ileewe girama.

'Mo ni lati mura si'

Frederick l'orukọ ọmọ naa, o si jẹ ọkan lara ogunlọgọ awọn ọmọ t'oun tiraka lati j'eeyan lai si oluranlọwọ.

Ọpọ lara wọn wa lati awọn ibudo t'awọn to sa kuro nile wọn lẹyin ti Naijiria jọwọ ilu Bakassi to kun fun epo rọbi fun orileede Cameroon to lmule ti i llyin idajọ ile ẹjọ agbaye.

Awọn to ku niwọn pe ni ajẹ, ti awọn mọlẹbi wọn si ti pa wọn ti - eyi jẹ ohun to wọpọ ni ipinlẹ Akwa Ibom.

Sugbọn Fredrick, lotitọ ati lododo, ni mọlẹbi.

Yaara kan loun gbe pẹlu iya rẹ. Ọugbọn iya naa ti fi ibẹ silẹ lati bi osu mẹjọ saaju, to si jẹ wipe oun lo n gbs bukaata ara rẹ.

Okina ni ,"Lootọ lo wa ninu akisa, sugbọn ẹnu ya mi pẹlu bi o ṣe gbọn fefe."

Image copyright GOVERNMENT HOUSE MEDIA
Àkọlé àwòrán Okina ti wa ni yunifasiti bayii

Bi ọpọlọpọ ọmọ, Frederick ati ọrẹ rẹ Kelvin n ri ounjẹ oojọ wọn l'atara agbe ṣiṣe lọsan.

Lẹyin eyi, wọn a maa fi okiti tita da awọn eniyan laraya lawọn ile ọti t'ilẹ ba ti ṣu.

Okina bẹrẹ si ni bẹ wọn wo lojoojumọ, a si maa mu nkan ipanu dani fun wọn.

"Ibaṣepọ to wa laarin wa kọja ọrọ ounjẹ ati owo, o dalori i itakurọsọ ọ wa."

Ṣugbọn Okina ko fi bẹ ẹ ni owo lọwọ.

Oun ṣiṣẹ ni ṣọọbu aranṣọ kan lati maa ri owo pẹẹpẹpẹ lasiko igba naa t'oun duro de iwe igbani wọle si yunifasiti.

Afojusun rẹ ni lati di oniṣẹ adani, ati olokoowo katakara ile ati ilẹ.

Ṣugbọn, o mọ wipe awọn ọmọdekunrin naa nilo iranlọwọ, nitori eyi lo fi tọ arakunrin kan, Inyang Edem, ti wọn jọ n jọsin nileejọsin kan na lọ, onitọhun si gba lati fun ni owo ti yoo gbs bukaata eto ẹkọ ati awọn nkan eelo mi i fun Frederick ati Kelvin.

"Lẹyin ti mo da awọn ọmọde mejeeji pada s'ileewe, ko si ibojuwẹyin fun mi mọ. Mo si kuku fi ara mi ji fun wọn."

Okina ba awọn ọmọde kan to maa n patẹ ere n'ikorita kan to wa ni itosi ile rẹ, o si maa n lo ọpọlọpọ wakati lati ba wọn takurọsọ.

Ni ọjọ kan, bi o ṣe p'ẹyinda lati maa lọ, ọmọ kan gba a lọwọ mu.

Eero Okina ni pe ọmọ naa fẹ tọrọ owo ni.

"Ṣugbọn, o ni ẹgbọn, ẹ jọwọ, ẹ pada wa."

'Ko si ẹni to ni lati yan ọ'

Loju kan naa, Okina pinnu ninu ọkan rẹ lati ṣe ju t'atẹyin wa lọ fun awọn ọmọ naa.

Bi o ṣe mọ wipe gbigbe ọrọ naa wa ọna ti o tọ yoo ran an lọwọ lati ri iranlọwọ gba si, lo mu ki o da Street Priests Inc (awọn alufa to n gbe loju popona) silẹ.

"Lasiko yii, ti awọn eniyan n w'oju ijọba tabi alufa lati mu ayipada ba awujọ, iwọ naa le ṣe iranlọwọ pẹlu nkan ti o ni, ni ibikibi ti o ba wa."

Image copyright STREET PRIESTS
Àkọlé àwòrán Inyang Edem (ninu asọ pupa) lo ran Okina lọwọ lati san owo ileewe awọn ọmọ akọkọ

O ṣalaye pe, "Ko pọn dandan ki ẹnikẹni fi aami ororo yan an ọ. Nitori eyi, ni wọn fi n pe wa ni Awọn Alufa oju popona."

O tẹsiwaju lati maa bẹ awọn ọmọde t'oun gbe lawọn oju opopona lawọn agbegbe mi i to wa ni ilu Calabar, ko si pẹ ti o fi di gbaju-gbaja laarin wọn, debi wipe, niṣe ni wọn maa n sare pẹlu idunnu lọ ọ pade bọọsi tabi takisi ti wọn ba ri i ninu rẹ.

'Mi o ti jingiri'

Lẹyin ọdun mẹta, Okina to jẹ ẹni ọdun mejidinlogun ti o ti di akẹkọọ nipa amojuto okoowo ni fasiti ilu Calabar bayii ti gba gbogbo ọna lati ri owo ti awọn okoolerugba din maarun awọn ọmọde yoo fi kawe, o si tun ni aadọta eniyan ti o yọ nda ara wọn.

O ni, "Mi o ni lero lati wa iṣẹ kankan. Ṣugbọn, maa kuku fi eyi ṣiṣẹ ṣe."

Adaobi Tricia Nwaubani:

Image copyright ADAOBI TRICIA NWAUBANI

"Igbeaye irọrun oun funraarẹ f'orisanpọn nigbati obi rẹ tuka"

Ipinnu rẹ yanilẹnu, ti a ba ni k'awo awọn idojukọ ti Okina ti ni pẹlu idasilẹ Street Priests.

Fun apẹẹrẹ, ọmọdekunrin ti o ku diẹ ki wọn gba ẹmi l'ẹnu rẹ nitori afọwọra; ọkan to daku rangbọndan s'ẹgbẹ titi fun wakati mẹrinlelogun o le lẹyin ti o mu egboogi oloro ni amu ju; ati awọn mẹta mi i ti opo ina to wo lulẹ tẹ pa lẹẹkan na.

Omiran tun ni ti ọmọdekunrin kan to bọ lọwọ awọn afiniṣetutu, eyi ti oju rẹ kun fun apa ada ti wọn gbiyanju lati fi da a duro.

Okina ni, "Awọn eniyan a maa ni wipe ọmọ lile l'awọn ọmọ t'ohun gbe lojupopona, ṣugbọn mo mo mọ wipe wọn kii ṣe ọmọ lile.

"Awọn ọmọde wọnyii maa n di ọmọ lile nipa bi wọn ṣe n ri ti awọn ọrẹ wọn n ku.

"Wọn a si sọ ninu ọkan wọn pe: Aye o naani wa, kilode ti ao fi naani rẹ?"

Okina ni iriri pe ki ẹnikẹni maa naani ẹni.

Igbeaye irọrun rẹ wa si opin nigbati iya ati baba rẹ kọ ara wọn silẹ.

Iya rẹ ko jade n'ile, ṣugbọn baba rẹ fi dandan gba oun ati awọn arakunrin rẹ mejeeji silẹ.

Image copyright STREET PRIESTS
Àkọlé àwòrán James bẹrẹ si ni ran awọn ọmọde lọwọ nigbati o wa l'ọmọ ọdun mẹẹdogun

Nitori ibanujẹ ọkan rẹ, o bẹrẹ si ni lo akoko rẹ l'ode , o si n darapọ mọ awọn ti o ṣe apejuwe wọn gẹgẹbi "ọrẹkọrẹ".

Laipẹ, ko ṣe daada nileewe mọ, a si maa fa wahala loorekoore.

"Awujọ maa n yara lati pe awọn eniyan ni ẹni buruku tabi ẹni rere. Awọn eniyan kii wa ẹni ti yoo sọ fun wọn wipe nnkan ti awọn n ṣe ko dara.

"Wọn n wa ẹni ti yoo gbe wọn jade."

Omije

Ṣugbọn, iranlọwọ Okina ko jina si: Ibatan rẹ kan lati Eko ṣe koriya fun un.

Okina ni, "O maa n nawọ ọrẹ awọn nnkan eto ẹkọ si awọn ọdọ t'owa ni awọn ileewe ati awọn bareke to wa ni ipinlẹ Eko. Eyi jẹ imoriwu fun mi.

"O tun jẹ ẹni to ni ọgbọn lori, o si tun ni afojusun."

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

O tun ni, "Ọpọlọpọ awọn ti o fi ara wọn jin fun itọju Street Priests jẹ awọn akẹẹgbẹ mi nileewe nigba kan, wọn si mọ bi iwa mi ṣe buru to nigba naa, ati ayipada rere ti o ti de ba mi.

"Wọn maa n sọ eyii fun awọn ọmọde naa, itan igbesiaye mi a si maa fun wọn ni ireti."

Iya rẹ naa fi ara rk jin pẹlu bi o ṣe maa n kọ awọn ọmọ naa ni ede gẹẹsi. Ọdun ti o kọja ni baba rẹ ku.

Image copyright STREET PRIESTS
Àkọlé àwòrán Okina ni erongba lati fẹ ajọ rẹ loju si

Ajọ Street Priests ti na iyẹ rẹ de ọdọ awọn ọmọde ti o ṣeeṣe ki o sọ ojupopo di ile, fun apẹẹrẹ: awọn t'ohun gbe ni awọn ibudo ifiniwọsi awọn ogunlende.

Ni bayi, ara iṣẹ ti ajọ naa n ṣe ni pipolongo fun ẹtọ awọn ọmọde, eto ilanilọyẹ fun awọn araalu lori ẹtọ awọn ọmọde, to di mọ ipese ibudo ti aabo yoo ti wa fun awọn ọmọde.

Eyi ti o kẹyin yii ni ipenija rẹ pọju nitori wipe awọn eniyan kii fẹ fi ile wọn haya fun ohunkohun ti o ba niiṣe pẹlu awọn ọmọ t'ohun gbe lojupopo.

O ni, "Ipinnu mi ni wipe ki a ri ibi ti a le pe ni tiwa."

Ni oṣu kejila 2017, Street Priests ṣeayẹyẹ kan lati fi imoore han si awọn oloore wọn. Edem, ti o fun Okina ni owo ileewe Frederick ati Kelvin gba ami ẹyẹ pataki, ti inu rẹ si dun debi wipe o bu s'ẹkun.

Okina ni, "Nigba ti o fun mi ni owo naa, ko mọ wipe oun n bẹrẹ nnkan ti o di nla loni."