Aarẹ Cyril Ramaphosa s'adehun igba ọtun fun South Africa

Aarẹ Cyril Ramaphosa s'ọrọ akọkọ lori ipo ti orilẹede naa wa ni ile igbimọ as'ofin ni igboro Cape Town, South Africa, ni ọjọ kẹrindinlogun osu keji, ọdun 2018 Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Cyril Ramaphosa, ẹni ọdun 65, jẹ okan lara awọn oselu ti wọn ni owo ju ni orilẹede South Africa

Aarẹ orilẹede South African tuntun, Cyril Ramaphosa, ti s'ọrọ nipa "igba ọtun" ninu ọrọ rẹ akọkọ nipa bi orilẹede naa ti wa ni ile igbimọ asofin orilẹede naa.

Ọgbẹni Ramaphosa, ti wọn bura fun ni ọjọbọ, se adehun ati gb'ogun ti iwa ibajẹ.

O si tun s'ọrọ nipa kikan titun ilẹ pin l'oju, pẹlu sise apejuwe bi yoo ti mu idagba s'oke ba oro aje orilẹede naa ati bi yoo ti pese ise.

Assaju rẹ ni ipo aarẹ, Jacob Zuma, fi ipo silẹ ni ọjọru lẹyin igba ti ẹgbẹ ANC ton s'akoso orilẹede naa ko ni papa mọra.

Related Topics