Ọjọgbọn Akinwunmi Ishola pa'poda lẹyin ọdun mọkandinlọgọrin

Oloogbe Akinwunmi Ishọla Image copyright @MobilePunch
Àkọlé àwòrán Oloogbe Ishọla lo kọ iwe Ẹfunsetan Aniwura

Ọjọgbọn Akinwunmi Ishola ti d'oloogbe, ọmọdun mọkandinlọgọrin ni wọn.

Gẹgẹbi iroyin iku rẹ se tẹ BBC Yoruba lọwọ, ọjọgbọn Akinwunmi Ishola ṣalaisi ni owurọ ọjọ abamẹta ni ilu Ibadan.

Ogbontarigi ayaworan ati olukọni iṣẹ ori-itage, Tunde Kelani ṣe idaro ọjọgbọn Akinwunmi Ishola ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ BBC Yoruba.

Baba naa ṣaisan fun igba diẹ ṣaaju ki o to pa'poda lowurọ oni.

Oloogbe Ishola jẹ ẹni ti o gbajumọ fun iṣẹ iwe-kikọ rẹ ati igbega ede Yoruba.

Lara awọn iwe ti oloogbe naa ko ni "Ẹfunṣetan Aniwura", "Madam Tinubu" ati ogbufọ fun awọn iwe ti ọjọgbọn Wole Soyinka kọ si ede Yoruba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTunde Kelani k'ẹdun iku Akinwunmi Ishola

Ọjọgbọn Akinwunmi Ishola (1939 - 2018)

  • Olukọni to yanranti, onkọwe agba lorilẹede Naijiria ti o ṣiṣẹ fun igbega ede Yoruba
  • Wọn bii nilu Ibadan ni ọdun 1939, ti o si lọ si Ile-ẹkọ Methodist ati Wesley College.
  • O kọ ẹkọ ni ile ẹkọ giga fasiti ti Ibadan, ti akẹkọgboye ninu ede Faranse.
  • O tun kẹkọgboye ninu ede Yoruba ni Ile-iwe giga fasiti ti Eko ni ọdun 1978 ṣaaju ki o to bẹrẹ iṣẹ ijinlẹ gẹgẹbi olukọni ni ile ẹkọ giga fasiti ti Obafemi Awolowo.
  • Isola kọ iwe akọkọ rẹ, Efunsetan Aniwura, ni ọdun 1961 ati 1962 nigbati o jẹ ọmọ ile iwe ni Ile-ẹkọ giga fasiti ti Ibadan.
  • Ni ọdun 2000, wọn fun un ni ẹyẹ National Merit ati Ẹlẹgbẹ ti Ẹkọ Ile-ẹkọ giga ti Naijiria.