Awọn maalu sediwọ fun ọkọ ofurufu nilu Akurẹ

Aworan awọn maalu kan ni ileese Dangote Image copyright Getty Images

Awọn maalu kan ti wọn rin wọ papa ọkọ ofurufu to wa ni Akurẹ ni ipinlẹ Ondo dina ati balẹ fun baalu ileesẹ Airpeace kan.

Ileesẹ ton s'amojuto awọn papa ofurufu ni Naijiria (FAAN) sọ wipe baalu naa ko le ba silẹ fun isẹju diẹ nitori awọn maalu naa.

Lori faran Twitter rẹ, ileesẹ FAAN so wipe kiakia ni wọn le awọn maalu naa kuro lojuona ti wọn si fun baalu naa l'ase ati ba.

Ileesẹ naa se ileri wipe oun yoo di ọna ti awọn maalu naa gba wọ inu papa naa nitori ki iru rẹ ma ba waye mọn.

Image copyright Getty Images

Lẹnu ijọ mẹta yi ọrọ asa idaranjẹ n mu ariyanjiyan wa inu awujọ ni Naijiria.