Fathia Balogun: Kò sí ẹni tó bá mi lò pọ̀, kó tó fún mi ní isẹ́

Gbajú-gbajà òsèré tíátà, Fatia Williams, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Fathia Balogun, lásìkò tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ní, orúkọ̀ tó bá wu òun ni òun leè jẹ́, àmọ́ ọ̀kan náà ni Fathia Balogun àti Fathia Williams, ìlò wọn sì wà lọ́wọ́ isẹ́ tí òun bá ń se.

Ó ní ìwọ̀n owó tí òun ń rí nínú isẹ́ ere síse mọ́ òun lọ́wọ́, tí òun kò sí mú isẹ́ míì mọ.

Bákan náà ni Fathia sàlàyé pé òun kò fẹ̀yìn balẹ̀ fún ẹnikẹ́ni rárá, kí òun tó gba isẹ́ tíátà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: