Shekau: Ileesẹ ologun nfẹ oku abi aaye rẹ

Ogagun Buratai atawọn ọgagun miran nigbo Sambisa Image copyright @HQNigerian Army
Àkọlé àwòrán Ileesẹ ologun yoo kọ oniruuru ibudo sigbo Sambisa lati gbakoso ibẹ patapata

Olori ọmọogun oriilẹ l'orilẹede Naijiria, Tukur Buratai ti rawọ ẹbẹ s'awọn ọmọ ogun orilẹede yi lati gbe Abubakar Shekau, tii se olori igun kan ninu ikọ adunkoko mọni Boko Haram, wa fun oun ni aaye abi ni oku.

Ọgagun Buratai parọwa yi nibudo Camp Zero, tii se ibujoko ibuba tẹlẹ f'awọn adunkoko mọni naa ninu igbo Sambisa lasiko abẹwo to se sawọn ọmọogun naa.

Awọn ibudo miran ti Buratai tun s'abẹwo si ninu igbo Sambisa ni Bita ati Tukumbere, ti gbogbo awọn adunkoko mọni ti fẹsẹ fẹẹ nibẹ

"Ẹ jẹ ki n ki yin ku oriire, amọ o yẹ ka kọja lọ s'ibiti ọkunrin ọdaran yi, Shekau wa, ka si mu laaye. Mo fẹ kẹ bami muu."

"Bakannaa ni aarẹ orilẹede yi ati oludari agba fun ileesẹ ologun orilẹede yi n ki yin ku oriire lori bi ẹ se gba igbo Sambisa. Ni tiwa, a ti de opin akanse ikọlu yi, eyiti ise lile awọn adunkoko mọni kuro ninu igbo Sambisa."

Ọgagun Buratai ti wa seleri pe ileesẹ ologun yoo mu ayipada rere ba igbo Sambisa, ti wọn yoo si sọ igbẹ rẹ digboro. Ati wipe, wọn yoo se agbekalẹ oniruuru ibudo awọn ologun sinu igbo ẹrujẹjẹ naa.