Iceland n fẹ fagile abẹdida sugbọn olori ẹsin kan ni ko tọ suna

Awọn eeyan kan duro, ọkunrin kan gbe ọmọ kan dani ti wọn n da abẹ fun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Labẹ ofin ti wọn n gbero yii, ijiya ọdun mẹfa n bẹ ni ikalẹ lorilẹede Iceland fun ẹnikẹni to ba da abẹ fun ọmọkunrin

Asiwaju ẹsin, musulumi kan ni orilẹede Iceland ti koro oju si igbesẹ eyi ti wọn n gbe lorilẹede naa lati fi ofin de dida'bẹ fun awọn ọmọ ọkunrin.

Oju ti asiwaju ẹsin naa, Ahmad Seddeeq fi wo ọrọ ọhun ni wipe o tako ominira ẹsin.

Ahmad Seddeeqto jẹ imaamu ni ibudo asa ẹsin Islam to wa ni orilẹede Iceland ṣalaye fi BBC wipe ọkan gboogi lara ilana ẹsin Islam ni asa dida abẹ fun ọmọ ọkunrin jẹ ati wi pe yoo jẹ ohun to buru jai lati wa lẹ ontẹ iwa ọdaran mọ asa naa lara.

Abadofin kan to wa niwaju ileegbimọ asofin orilẹede Iceland lọwọlọwọ bayii lo n fonrere rẹ wi pe ki wọn maa fi ijiya ti o to ọdun mẹfa jẹ ẹnikẹ ti aje rẹ ba si mọ lori wi pe o n da abẹ fun ọmọde yala nitori ọrọ ẹsin tabi ọrọ asa.

Awọn to n se agbatẹru ofin yii fi ọrọ ọhun se akawe pẹlu igbesẹ dida'bẹ fun awọn ọmọbinrin ti wọn si ni ko si bameji ju wipe igbesẹ naa n tẹ ẹtọ awọn ọmọ ọkunrin loju mọlẹ.

Bakannaa lawọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ gbogbo to rọ mọ ẹsin Juu pẹlu ti koro oju si igbesẹ yii.

Related Topics