Nnamdi Kanu kò sí ní orílẹ̀èdè wa rárá o- Ìjọba Orílẹ̀èdè Israel

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Elliot Ugochukwu-Ukoh

Orilẹede Israel ti ṣalaye pe aṣiwaju ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu ko si ni orilẹede naa.

Nnamdi Kanu sọọ ninu ọrọ kan to sọ lori redio laipẹ yii pe orilẹede Israel ni oun wa lọwọlọwọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ orilẹede Israel ni naijiria, ṣalaye fun BBC pe, ni ti awọn o, Kanu ko si ni orilẹede Israel.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nnamdi Kanu ti awọn alaṣẹ ati agbofinro lorilẹede Naijiria ti n wa lati ọdun to kọja kede lori redio laipẹ yii pẹ ọpẹlọpẹ orilẹede Israel ni oun ṣi fi wa.

Bakan naa ni oreilẹede Israel ṣalaye pe o ṣeeṣe ki fọnran aworan ti awọn kan n fihan pe Kanu n gbadura ni orilẹede Israel jẹ eyi ti o ti pẹ.

Oniruru ibeere lo ti n waye lori ọna ti Ọgbẹni Nnamdi Kanu gba jade kuro lorilẹede Naijiria pẹlu bi o ti ṣe ti ko awọn iwe irinna ti orilẹede Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi to ni silẹ fawọn agbofinro.

Ni ọdun 2015 ni wọn fi ẹsun iditẹ mọ ijọba kan Nnamdi Kanu, o si ti lo odun kan ati abọ ni ahamọ.

Àkọlé àwòrán,

Fani Kayọde ni igbagbọ ohun ninu iṣọkan orilẹede Naijiria ko yẹsẹ rara.

Fani Kayọ̀de ṣàlàyé ìdí àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú IPOB

Fani kayọde ti ṣalaye pe kii ṣe nitori ati pin orilẹede Naijiria ni oun ṣe n fẹran Nnamdi kanu to jẹ aṣiwaju ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede olominira Biafra, IPOB.

Fani Kayọde ni igbagbọ ohun ninu iṣọkan orilẹede Naijiria ko yẹsẹ rara bi o tilẹ jẹ wi pe oun ati olori ẹgbẹ naa sun mọ ara wọn pẹkipẹki.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ to ba BBC news sọ nilu Eko, sọ lori ibanisọrọ kan to sọ pe o waye laarin oun ati Nnamdi Kanu lori piparapọ lati le Buhari sita, eleyi ti ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ IPOB ti jade lati sọ pe olori ikọ IPOB ko ba ẹnikẹni ni adehun ati le ẹnikẹni kuro ni ipo, oloye Fani kayọde ni ohun ko ni ero kankan lati doju ijọba tiwantiwa delẹ lọnakọna bikoṣe lati tubọ mu ki eto iṣejọba o tun gbilẹ daadaa ninu orilẹede Naijiria to wa ni isọkan.

"Mo nigbagbọ ninu atunto ilana iṣejọba lorilẹede Naijiria, mo ni igbagbọ ninu iṣọkan orilẹede Naijiria, mo si tun ni igbagbọ ninu eto iṣejọba tiwantiwa."

O ni lootọ ni oun faramọ awọn ẹgbẹ naa nitori iwa ko tọ ti ijọba de ijọba n fi oju wọn ri ṣugbọn oun ko lee tẹlẹ ọna miiran ju iṣọkan orilẹede Naijiria lọ.

"Mo lee faramọ Nnamdi Kanu nitori ohun ti ẹgbẹ rẹ n ja fun ati nitori oun ti oju awọn eeyan rẹ n ri, ṣugbọn mi o kii n ṣe ọmọ ẹgbẹ IPOB, ọmọ orilẹede Naijiria ni mo jẹ."

Nnamdi Kanu ti ṣàlàyé bí ó ṣe rìn lẹ́yìn ọdún kan tó dàwátì

Àkọlé fídíò,

Nnamdi Kanu ti ṣàlàyé bí ó ṣe rìn lẹ́yìn ọdún kan tó dàwátì

Olórí ẹgbẹ́ tó ń polongo fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀édé Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu ti sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ọdún kan tó dàwátì.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ tó fi síta lórí rẹ́díò Biafra, Nnamdi Kanu ní òhun kò mọ̀ọ́mọ̀ sá nílùú bí kìí bá ṣe wí pé iléesé ọlógun Nàìjíríà fẹ́ pa òhun lo mu ki oun sa nilu.

''Mi o mọmọ sa fun ile ẹjọ.Won fẹ pami ni mo fi sa nilu''

Nnamdi Kanu dupe lọwọ awọn alatilẹyin rẹ to duro ti lasiko ti o fi sa nilu.

O ni ''Mo dupẹ lọwọ Sẹnẹtọ Abaribe, alagba Ayo Adebanjọ to jẹ olotito eeyan ati awọn alatilẹyin mi''

Bakanna lo ni IPOB wa digbi pẹlu Gomina Ipinlẹ Ekiti ana ,Ayo Fayose ti ajọ EFCC n ba se ẹjọ.

Ó ti pé oṣù mẹ́tàlá lẹ́yìn tí àwọ́n alátìlẹ́yìn rẹ̀ ní ìkọlù pẹ̀lú àwọn ológun ní ìlú Abia, ìhà Gúúsù-Ìlà Oòrùn orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Ifeanyi Ejiofor tó jẹ́ agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Kanu ti saaju sọ wí pé olórí IPOB náà ti pe òun lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ lẹ́yìn fídíò bí ó ṣe ń gbàdúrà ní ilẹ̀ Jerusalem lórí ìtàkùn ayélujára.

Lẹ́yìn ọdún kan, wọ́n rí Nnamdi Kanu ni Israel

Oríṣun àwòrán, Elliot Ugochukwu-Ukoh

Fidio kan ti ṣafihan ọkunrin kan ti wọn sọ pe o jọ Nnamdi Kanu, to jẹ olori ẹgbẹ to n polongo fun idasilẹ orilẹede Biafra, IPOB ni orilẹede Israel.

Wọn ri nibi to ti n gbadura ni ilana ẹ̀sìn Juu ni orilede Israel. Igba akọkọ niyii ti yoo yọju si gbangba lati dun 2017 ti ileeṣẹ ologun Naijiria ti kọlu ilu abinibi rẹ, Afaraukwu, to wa ni ipinlẹ Abia.

Botilẹjẹ wi pe ileeṣẹ BBC ko ti le fọwọ sọya pe Kanu lo wa ninu fidio naa, awọn kan to sunmọ ọ ti a ba sọrọ fidirẹ mulẹ fun wa pe oun lo wa ninu rẹ.

Ninu oṣu Kẹsan an, ọdun 2017 ni Kanu di awati lẹyin ti ijọba orilẹede Naijiria tọka si ẹgbẹ IPOB gẹgẹ bi agbesunmọmi. Ti awọn ọmọ ogun Naijiria si kọlu ilu abinibi rẹ ninu eto akanṣe kan ti wọn pe ni 'Operation Python Dance', eyi to mi ko ṣoro lati mọ ibi to wa titi di asiko yii.

Awọn eniyan ẹ̀yà Igbo n fi sun kan ijọba orilẹede Naijiria pe wọn n dẹ́yẹ si awọn, eyi to mu ki wọn o maa ja fun idasilẹ orilẹede olominira Biafra.

Ipolongo fun Biafra lo fa ogun abẹle to waye ni Naijiria l'ọdun 1967. Ọpọlọpọ eniyan lo padanu ẹmi wọn sinu ogun naa.

Iyawo kanu sọ pe ẹ̀yà Igbo ko ni i dibo ti Kanu ko ba jẹ́ riri

Àkọlé fídíò,

Idibo ko ni waye ti wọn ko ba mu ọkọ mi jade

Ijọba Naijiria sọ pe awọn ko mọ ibi ti Nnamdi Kanu wa

Ijọba orilẹede Naijiria ti sọ wipe awọn ko mo nkankan nipa ibi ti adari ikọ Ipob, Nnamdi Kanu farapamọ si lati igba ti Ikọ ọmọogun Naijiria ti se ikọlu "Operation Python Dance" lagbegbe Ila-Oorun Gunsu orilẹede Naijiria.

Minisita feto iroyin ati asa, Lai Muhammed lo fesi bayi nigba to n ba akọroyin BBC Igbo sọrọ lori ẹsun ti iyawo Nnamdi Kanu, Nchechi Okwu-Kanu fi kan ijọba apapọ, wipe awọn lo mọ ibi ti ọkọ ohun wa, lati bi osu die sẹyin.

Àkọlé àwòrán,

Ijọba Naijiria sọ pe awọn ko mọ ibi ti Nnamdi Kanu wa

Muhammed ninu ọrọ rẹ sọ wipe ohun ko mọ irinajo Kanu, ati wipe iyawo rẹ nikan lo le sọ pato ibi ti ọkọ rẹ wa.

O fikun wipe, ohun ko figba kan ni itakurọsọ pẹlu iyawo Nnamdi Kanu ri, atiwipe ohun ko si nipọ lati wa olori ikọ Ipob naa jade.

Minisita feto iroyin ati asa naa wa rọ iyawo Nnamdi Kanu lati kede ibi ti ọkọ re wa sita, nitor iwipe iyawo rẹ nikan lo mọ ibi to wa.

Ti a ko ba gbagbe, ijọba apapọ ti pe ẹgbẹ Ipob ni ẹgbẹ agbesunmọmi, ti wọn si fikun wipe awọn yoo fi panpẹ ọba mu enikẹni to ba n sọ kaakiri wipe ọmọ ẹgbẹ naa ni oun.