Wọle Soyinka: Ti mo ba dara pọ m'ẹgbẹ Obasanjọ, wọn gbọdọ yẹ ọpọlọ mi wo

Wọle Soyinka: Ti mo ba dara pọ m'ẹgbẹ Obasanjọ, wọn gbọdọ yẹ ọpọlọ mi wo

Ọjọgbọn Wole Soyinka ba BBC Yoruba sọrọ lori ọrọ oṣelu ni Naijiria.

O wipe kaka ki oun darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ti Oloye Olusegun Obasanjo da silẹ, ki wọn kuku gbe oun lọ fun ayẹwo ọpọlọ.

Siwaju si, Ọjọgbọn Soyinka sọ pe asiko ti to fun awọn ọdọ lati fa enikan lara wọn kale fun ipo adari ni Naijiria, wọn si wipe awọn agbalagba bi ti wọn yoo gbaruku ti iru ẹni bee leyin.

O sọ pe ki wọn ni ki awọn agbalagba lọ wa bi joko si ki awọn ọdọ le raye sejọba.

Bakana lori leta oloye Ọbasanjọ ati ogagun Babangida, Soyinka sọ wipe o yẹ ki awọn eniyan maa funra ti awọn ologun ba ti n kọlẹta si ara wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: