Awọn akẹkọ sa wọ'gbo lati farapamọ n'ipinlẹ Yobe

Iko omo ogun orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn omo ogun Naijiria ti nkoju iko Boko Haram lori ipaniyan ati ijinigbe

Nse ni awọn ọmọ ile ẹkọ girama ti ilu Damaturu ni ipinlẹ Yobe bẹ wọ inu igbo lọ lati sapamọ fun awọn ajinigbe ati awọn apaniyan ti wọn fura si wipe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Boko Haram nigbati wọn tun gbe ise wọn de ni alẹ ọjọ aje.

Iṣẹlẹ yii waye ni abule Dapchi lagbegbe Damaturu nigbati awọn afipagbeni ya wọ abule naa ninu ọkọ nla mẹfa ni deede agogo meje alẹ ti wọn si bẹrẹ si nii yinbọn.

Awọn agbenipa yii sọ ina si ọpọlọpọ awọn ile ti awọn olugbe wọn si sa asala lọ sinu igbo lati farasin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ipinle Yobe wa lara awọn ipinlẹ ti iko Boko Haram gbogun ti

Eeyan kan ti ọrọ naa se oju rẹ fi to ileeṣẹ AP leti lati inu igbo to farapamọ si sọ wi pe oun ko lee sọ boya awọn agbenipa yii ji eyikeyi ninu awọn ọmọ ilewe girama naa gbe tabi bẹẹkọ.

Kọmisọna fun ọlọpa ni ipinlẹ Yobe, Abdulmaliki Sunmonu fidi ikọlu naa mulẹ. O sọ pe awọn ti ko ikọ ọlọpaa lọ si agbegbe naa lati pese aabo to peye.