EFCC: Patience Jonathan gbọdọ foju wina igbẹjọ

Patience Jonathan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Patience Jonathan ti wa nile ẹjọ pẹlu ajọ EFCC lori oniruuru ẹsun kiko owo ilu sapo ara rẹ

Ajọ to n gb'ogun tiwa ṣise owo ilu kumọkumọ lorilẹede Naijiria (EFCC) sọ wipe awọn ti yari fun aya aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Patience Jonathan pe o gbọdọ yọju s'ile-ẹjọ fun igbẹjọ nipa awọn owo tuulu ti wọn ba ninu awọn apo aṣuwọn rẹ.

Ajọ EFCC ti beere pe ko wa s'iwaju adajọ nibamu pẹlu ilana ofin to de igbesẹ idunadura nipa owo to wa lapo asunwọn rẹ.

Awọn oṣiṣe ajọ EFCC ko ti ni ẹri to daju nidi itọpinpin ati iwadi wọn nipa eniyan mọkandinlọgbọn ninu awọn eeyan ati ileesẹ mọkanlelọgbọn ti wọn fi ẹsun kan wipe wọn gbe owo to nfa awuyewuye naa sinu apo asunwọn Patience Jonathan, eyi to n fidi ahesọ ọrọ to nja nipa isẹlẹ naa mulẹ pe irọ ni pe awọn kan lo gbe owo naa sibẹ.

Amọ Agbẹnusọ fun ajọ EFCC, Wilson Uwajeren ko dahun ipe BBC Yoruba lati sọ ni pato ero ajọ naa lori ọrọ yii.