Ileeṣẹ ologun: Abubakar Shekau tun ti sa mọ wa lọwọ

Abubakar Shekau

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ogun mẹjẹ lati orilẹẹde Naijiria ati Cameroon ni wọn padanu ẹmi wọn ninu ikọlu naa

Iroyin to tẹ ile isẹ BBC lọwọ sọ wi pe awọn ọmọ ogun orilẹede Naijiria dawọ igbesẹ lati mu olori ikọ Boko Haram, Abubakar Shekau duro.

Ninu fọran fidio kan ti wọn fi sọwọ si ile iṣẹ BBC, awọn ọmọ ogun gbe ija wọ'nu aaye ibugbe Shekau ninu igbo Sambisa.

Ṣugbọn lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn bẹrẹ igbesẹ naa ni aṣẹ wa pe ki wọn dẹkun titọpinpin Shekau.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ikọ Boko Haram nkoju ijọba orilẹede Naijiria

Lẹyin orẹyin ni awọn agbesumọmi yin ado oloro ti wọn so mọ ọkọ lu awọn ọmọ ogun.

Ọmọ ogun meje lati orilẹẹde Naijiria ati Cameroon ni wọn padanu ẹmi wọn ninu ikọlu naa.

Ni igba ti awọn ọmọ ogun yoo fi korawọnjọ pada, Shekau ti salọ.

Ọkan lara awọn ọmọ ogun orilẹẹde Naijiria ṣe alaye oun toju wọn ri ninu fọran ohun ti wọn gba silẹ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: