Minisita f'eto ilera wipe ni awọn ipinlẹ ni iṣẹ lati ṣe lori iba lassa

Eku meji n jẹ eerun ounjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Minisita feto ilera ni ajumọse ni igbesẹ lati gbogun ti iba ọrẹrẹ

Awọn ijọba ipinlẹ ni lati tun ero wọn pa lori idagbasoke eto ilera bi orilẹede Naijiria ba fẹ ṣẹgun iba lassa to n fi ojojumọ gbalẹ gba oko bayii.

Minisita fun eto ilera lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Isaac Adewọle lo sọ eleyi ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Ọjọgbọn Adewọle ni alafo oun ọgbun ibanisọrọ to wa laarin awọn ijọba ipinlẹ ati awọn eeyan wọn lo n ṣokunfa bi wahala aarun iba lassa ṣe n fẹ oju sii lorilẹede Naijiria.

Iba ọrẹrẹ ti a tun mọ si iba lassa ti gbilẹ lorilẹede Naijiria fun asiko diẹ bayii eleyii to ti gba ẹmi ọpọlọpọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn eku maa n ko arun iba orere ran gaari

Ni ọjọ aiku ni iroyin tun kan wipe awọn mẹta miran tun ti di ero ọrun nipasẹ arun gbẹmi-gbẹmi yii.

Minisita feto ilera lorilẹede Naijiria ni ko dara bi pupọ awọn ipinlẹ ko se ni ibi ayẹwo to yẹ fun ayẹwo arun lassa ki wọn lee maa pẹka iroko rẹ ki o to maa gba ẹbọ.

Bakanna lo rọ awọn kọmisọna feto ilera kaakiri gbogbo ipinlẹ lorilẹede Naijiria lati rii wipe wọn ko jẹ ki eti awọn gomina wọn di si bi nkan ba se n lọ si lori gbigbogunti arun iba ọrẹrẹ yii.

Lori bi awọn eleto ilera paapaa julọ awọn dokita to n tọju awọn alaisan se di ẹni ti o nko arun yii bayii, ọjọgbọn Adewọle ni ohun to bani ninu jẹ pupọ ni pe awọn olutọju alaisan pẹlu ti ẹni to n ko aisan yii sugbọn o ke si awọn dokita ati awọn olutọju alaisan kaakiri orilẹede Naijiria lati tubọ maa da abo bo ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Minister f'eto ilera wipe gbigba awọn abẹrẹ ajẹsara le dẹkun iba pẹlu

Minisita fun eto ilera ni lọwọ ti a nsọrọ yii, ko din ni ipinlẹ mẹẹdogun ti aarun yii ti nja bayii, bakannaa lo ni ko di ni eeyan marundinlọgọfa ti iwadi ti fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti lugbadi aisan yii.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: