Awọn alẹnulọrọ ns'ọrọ loridasilẹ ileesẹ ọlọpa agbegbe

Awon olopa nso awon ti o n se iwode Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awon eniyan beru lilo olopa agbegbe fun nka miran

Ọrọ abo lorilẹede Naijiria ti di ohun to n kọ ọpọlọpọ laya.

Ni kopẹkopẹ yii ni igbakeji aarẹ lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo ti s'ọrọ sita wipe pẹlu gulegule ipaniyan ti o n f'ojojumọ waye yii, ohun ti yoo ṣe anfani fun orilẹede Naijiria naa ni idasilẹ ileesẹ ọlọpa agbegbe.

Ọrọ ti igbakeji aarẹ sọ kọ ni igba akọkọ ipe fun idasilẹ ọlọpa agbegbe tabi ti ipinlẹ lorilẹede Naijiria; ko si daju wi pe oun ni yoo jẹ opin titi di igba ti idasilẹ naa ba waye, iyẹn ti o ba maa waye rara.

Sugbọn ni bayii awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan ti n sọ ti inu wọn sita lori ọrọ naa.

Ọgbẹni Okey Nwaguma to jẹ asiwaju ẹgbẹ kan to n fọnrere atunṣe ileesẹ ọlọpa lorilẹede Naijiria, (Network on Police Reforms) ni ipe fun idasilẹ ọlọpa agbegbe tabi ti ipinlẹ ko jẹ tuntun sugbọn igbesẹ to dara ni pẹlu bi orilẹede Naijiria ti se tobi to.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ilaji gbogbo ọlọpa orilẹede Naijiria ti wọn ko si nidi isẹ igbofinro mọ

"Igbagbọ ọpọ ni wi pe Naijiria ti tobi ju lati ni ileesẹ ọlọpa oloju kan soso bi ti ileesẹ ọlọpa alapapọ to ni bayii. Awọn ipinlẹ n se ofin sugbọn wọn ko ni agbofinro to lee fi awọn ofin naa mulẹ pẹlu bi o se jẹ wi pe ofin to ba wu ileesẹ ọlọpa apapọ bayii ni wọn n sisẹ le lori."

Amọsa, oju miran ni Ọmọọba Mukaila Akinsemoyin fi wo ọrọ naa.

Ọmọọba Akinsẹmoyin ni, pẹlu awọn oloṣelu ti o wa lode lorilẹede Naijiria bayii, yoo nira lati ko agbara ọlọpa le ipinlẹ lọwọ.

Ọmọọba Akinsẹmoyin to jẹ ajafẹtọ araalu to yan atunto ileesẹ ọlọpa laayo ni ọrọ ọhun dabi ti alabahun to ni inu oun o dara ni, gbogbo aye lo ri bi ita rẹ gan an ṣe ri. O ni gbogbo aye lo ri iru ara ti awọn oloṣelu n fi ileesẹ ọlọpa apapọ da melomelo ni ti ọlọpa ipinlẹ lọwọ awọn oloṣelu orilẹede naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awon eniyan beru lilo olopa agbegbe fun nka miran

"Orilẹede Naijiria ko tii balaga to lati ni ọlọọpa agbegbe tabi ti ipinlẹ. Ohun to ṣee ṣe ni ki a ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ lawọn ipinlẹ ti ko ni jẹ ẹka ti yoo maa gbe ibọn dani."

Lorilẹede Naijiria loni, awọn eeyan ko fi bẹẹ ni igbagbọ ninu ileesẹ ọlọpa pẹlu oniruru ẹsun ikowojẹ, igbariba ati titẹ ofin mọlẹ lati tu awọn oloṣelu loju ati bẹẹbẹẹlọ.