Igbejọ Ipob: Ileẹjọ yoo gbọ ẹjọ Nnamdi Kanu lọtọ

Aworan Nnamdi Kanu Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán O ti to osu mẹfa ti wọn ti gburo Nnamdi Kanu sẹhin

Nnamdi Kanu ni wọn ko tii gburo rẹ lati igba tawọn ọmọ ogun orilẹede Naijiria yabo ile rẹ nibi osu mẹfa sẹhin.

Adajọ Binta Nyako tile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa nilu Abuja lo pasẹ bẹẹ nigba ti asaaju ikọ agbejọrofun igun olupẹjọ to fẹsun kan Ipob, Shuaibu Labaran sọ wipe, bi Kanu ko se yọju sile ẹjọ nfa ifasẹhin fun igbẹjọ ati ilọsiwaju lori ẹjọ naa.

Nnamdi Kanu ati ikọ rẹ ni wọn fẹsun onikoko marun kan, ninu eyi ti ẹsun iwa ọdaran ati iditẹ wa ninu rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIdibo ko ni waye ti wọn ko ba mu ọkọ mi jade

Kanu ni wọn ko ti gburo rẹ lati igba ti awọn ọmọ ogun orilẹede Naijiria yabo ile rẹ nibi osu mẹfa sehin, lọna a ti kapa awọn ajijagbara naa.

Sugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ Ipob ti wọn wa latimọle lo wa nibi igbẹjọ naa, ti adajọ si fi asẹ si wipe ki wọn gbọ ẹjọ Kanu lọtọ, ki igbẹjọ lee tẹsiwaju

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ikọ Ipob n ja fun ominira ilẹ Biafra

Lara awọn ọmọ ẹgbẹ Ipob to n jẹjọ ni Ogbeni Chidiebere Onwudiwe, Benjamin Madubugwu ati osise ileesẹ ibaraẹnisọrọ MTN, David Nwawuisi.

Laipẹ yii, nijọba apapọ fofin de ẹgbẹ Ipob, to npe fun idasilẹ orilẹede Biafra, tijọba si pe wọn ni ẹgbẹ adunkokomọni, pẹlu ileri wipe ẹnikẹni to ba darapọ mọ wọn, yoo ri ibinu ijọba.