Nimet: Ẹ ma tii dako nitori ojo akọrọ

Ọgbin agbado Image copyright @SuccessfulFarm
Àkọlé àwòrán Nimet ni ko si ohun tuntun ninu ojo akọr yi, igba ẹẹrun lo n kogba wọle

Ajọ to nwo sakun bi oju ọjọ ti ri, Nimet, ti sin awọn agbẹ ni gbẹrẹ ipakọ lati mase dako lasiko ojo akọrọ yi.

Awọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria lo ti nni iriri ojo lati bii ọsẹ meji sẹyin to fi mọ olu ilu ilẹ wa Abuja ati ipinlẹ Eko.

Ajọ Nimet ni ko si ohun to jẹ tuntun ninu ojo akọrọ to nwaye lasiko yi nitoripe bo se maa nwaye ree lasiko ti ẹẹrun ba n kogba wọle.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

"O yẹ kawọn agbẹ maa lo akoko yi lati fi palẹ oko mọ silẹ fun ọgbin ni, kii se lati maa gbin ire oko lakoko yi. Nitori akoko ojo ko ti wọle de patapata."

Ajọ Nimet salaye pe ooru to ndapọ mọ ọyẹ lagbegbe aarin gbungbun ariwa orilẹede yi lee sokunfa ojo nibẹrẹ ọdun.