Inec pẹlu awọn igbimọ idibo ipinlẹ nsepade lori lilo awọn ti ko to iboọ di

Ero idibo Naijiria Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán INEC pe'pade pẹlu awọn igbimọ idibo ipinlẹ lori idibo awọn ọmọde

Nitesiwaju igbiyanju lati dẹkun idibo awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko ti to d'ibo, ile-iṣẹ to n ṣakoso eto idibo idibo lorilẹede Naijiria ti pe ipade pẹlu awọn alakoso eto idibo nipinlẹ jakejado orilẹede yi ni oni - ọjọru nilu Abuja.

Ninu atẹjade kan ti o fi lede, agbẹnusọ fun alaga INEC, ọgbẹni Rotimi Oyekanmi sọ pe, "ipade pataki pẹlu awọn alakoso eto idibo ni awọn ipinlẹ (SIEC) yoo waye ni olu ile iṣẹ INEC nilu Abuja lọjọru lati agogo meji ọsan.

Bi o tilẹ jẹ pe Oyekanmi ko sọ idi ti ipade naa yoo fi waye, ajọ INEC ti fi aake kọri wipe oun ko ni ọwọ ninu akoso eto idibo ti o waye nipinlẹ Kano ni ọsẹ ti o kọja ati wipe iṣẹ awọn ajọ alakoso eto idibo ipinlẹ (SIEC) ni eyi.

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) jawe olubori ninu idibo abẹle ti o waye nipinlẹ Kano.

Faran fidio ti o se afihan awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to lati dibo gba ori afefe leyin idibo naa.

Alabojuto agba fun INEC, ọjọgbon Mahmood Yakubu lọsẹ to koja so wi pe awọn yoo tọpinpin ohun ti o ṣẹlẹ ninu idibo abẹle ti o waye nipinlẹ Kano.

Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán PDP npe fun ifiposilẹ alaga igbimo INEC

Ẹwẹ, awọn adari ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti bu ẹnu ẹtẹ lu igbimọ alakoso idibo (INEC).

Ẹgbẹ naa ti npe fun ifiposilẹ alaga ẹgbẹ naa, ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ki ẹlomiran si b s'ipo naa.

Alukoro ẹgbẹ PDP, ọgbẹni Kola Ologbondiyan sọrọ naa fun awọn oniroyin nilu Abuja lọjọ isẹgun nibi ti o ti tun fi ẹsun aiṣedeede oriṣiriṣi kan ajọ INEC.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: