Lasema: Ọkọ̀ epo kan tó ń da epo sílẹ̀ ló mú ká ti òpópónà náà pa

Oju ọna ti ijọba Eko ti pa

Iroyin kan to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo fi ye ni pe, ọkọ agbepo kan to ko epo petrol ti n da epo silẹni adugbo Ajao Estate nilu Eko ni idaji ọjọ Satide.

Isẹlẹ naa si lo se okunfa bi ijọba ipinlẹ Eko se kede pe ki wọn ti oju ọna naa ni kia-kia lati dena isẹlẹ ijamba ina, se onbọ̀, onbọ, àwọ̀n laa dẹ dee, amọ lojumọ toni, oju ni wọn n mu too.

Akọroyin BBC to se alabapade isẹlẹ naa ni igbesẹ yii ti n se okunfa sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ni adugbo yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìdíje ayò ọlọ́pọ́n, ta lòpè?

O ni awọn osisẹ to n dena isẹlẹ pajawiri ti de si agbegbe naa lati dena isẹlẹ ijamba ina to lee su yọ lagbegbe naa.

Bẹẹ ba si gbagbe, ọpọ igba ni tanka agbepo ti se okunfa ijamba ina ni ipinlẹ Eko, ninu eyiti ọpọ ẹmi ti baa rin.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun ajọ to n ri si akoso isẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko,Lasema, Ọgbẹni Tiamiyu Adesina, ẹni to sọrọ lorukọ ọga agba fun ileesẹ naa ni, ni kete ti wọn fi isẹlẹ tanka epo to n jo naa to awọn leti, ni awọn osisẹ Lasema ti wa nibẹ.,

Adesina ni awọn osisẹ panapana, awọn ọlọpaa ati awọn osisẹ ajọ Lasema lo wa nibudo ti tanka epo ti n da epo prtrol silẹ lọna ati dena ijamba ina.

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ninu iroyin miran ẹwẹ, Ọkọ baalu ile iṣẹ ofurufu Dana kan lati Abuja lọ si Port harcourt ti sa're kọja oju opo to si ya wọ inu igbo ni papakọ ofurufu Omagwa.

Ni ṣe ni wọn sare doola ẹmi awọn ti wọn wa ninu ọkọ naa lati inu igbo to ya si.

Awọn to ṣoju wọn ni ko sẹni to f'arapa ninu isẹlẹ naa.

Adari eto ipolongo fun ajọ to'n mojuto irina ọkọ ofurufu, Henriettta Yakubu fidi ọrọ naa mule.

O ni ''baluu Dana kan pẹlu nọmba 9J0363, ti o nrina Abuja si Port-Harcourt sare kọja papakọ ofurufu ni ilu Port-Harcourt"

"O da bi wi pe ojo arọọda to fẹ atẹgun lile lo ṣe okunfa rẹ''

''Ko si ẹni to farapa. Gbogbo awọn arinrinajo to wa ninu baalu naa ni wọn ri yọ.''

Lai pẹ yi ni ilẹkun ọkan ninu awọn baalu ile iṣẹ naa to gbera lati Eko si Abuja foyọ.

Lọdun 2012 ni ọkan lara awọn baalu Dana ja lori ofurufu ti eniyan mẹtalelaadọjọ padanu ẹmi wọn.