Ejo lo gb'owo mi ni Naijiria, anabọ lo kowo lọ ni Burundi

Eeyan kan n ka owo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Isẹlẹ owo pipoora ti n di lemọlemọ ni ilẹ Afirika

Njẹ ẹ ranti isẹlẹ ejo to gbe owo mi lorilẹede Naijiria laipẹ yii?

Iṣẹlẹ miran to jọọ ti waye lorilẹede Burundi sugbọn oogun abẹnu gọngọ ni wọn di ẹbi iṣẹlẹ yii ru o.

Boya ni o tilẹ ti gbọ nipa owo anabọ ri? Eleyii lo farahan ninu iroyin yii bi o tilẹ jẹ wipe o fara jọ iroyin ejo akowomi lorilẹede Naijiria, sugbọn owo anabọ ni ohun jẹ.

Iṣẹlẹ yii waye ni ile ifiweranṣẹ alabọde kan to wa ni agbegbe Cibitoke ni iwọ oorun orilẹede Burundi.

Gẹgẹbi iroyin ti ṣe sọ, ọkunrin kan wọ ileefiweranṣẹ naa pẹlu owo beba ẹgbẹrun mẹwa (eyi ti yoo jọ nkan bii ẹgbẹrun meji abọ naira) o si n beere fun iyoku owo rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEjo abami to n mu owo ni ajọ Jambu ni Naijiria

Agbowo ileefiweranṣẹ naa ko owo ti arakunrin yii mu wa pẹlu awọn owo miran to wa ni aapo ileeṣẹ naa.

Amọṣa, nigba ti yoo fi yẹ owo naa wo pada, gbogbo miliọnu mẹtalelogun owo ilẹ Burundi (ti yoo ja si miliọnu meji naira o le diẹ) to wa nibẹ ti poora pẹlu owo ti arakunrin yii mu wa.

Bakannaa ni wọn ni arakunrin to mu owo ọhun wa pẹlu ti poora lẹyẹ o sọka.

Alukoro ileesẹ ọlọọpa lorilẹede naa ti fi idi isẹlẹ yii mulẹ to si ni awọn ọkunrin meji ni wọn ti fi si ahamọ lori ọrọ naa titi di igba ti iwadi yoo fi pari.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: