Ileeṣẹ aarẹ sọ wipe ara ọmọ aarẹ Buhari, Yusuf Buhari n m'okun

Aworan Yusuf Buhari saaju ijamba alupupu to fii larapa Image copyright @YusufBuhari_
Àkọlé àwòrán Ajalu ijamba alupupu ba Yusuf Buhari l'ọjọ ọdun keresimesi l'Abuja

Aarẹ orilẹede Naijiria ti tako iroyin to n tan ka wipe ọmọ rẹ, Yusuf Buhari, ti papoda.

Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari lori faran igbalode ati ẹro ayalujara, Bashir Ahmad, sọ fun BBC wipe: "Ara Yusuf Buhari n tunbọ n m'ọkun si ni ilewosan to tin gba itọju ni orilẹede Germany ati wipe awọn dokita ṣi tun wo ori to fi gba ati ẹsẹ rẹ."

Awọn opo ayelujara kan ko iroyin wipe ọmọ aarẹ Naijiria naa ṣ'alaisi ni irọlẹ ọjọ isẹgun.

Ṣugbọn Bashir sọ wipe iroyin naa ki ṣe otitọ, o si ṣ'afikun wipe "lana gan (ọjọ isẹgun) mọ sọrọ pẹlu ọmọ iya rẹ to n tọju rẹ n'ilewosan Germany to ti n gba itọju, o si sọ fun mi wipe ara rẹ n m'okun sii."

Ṣugbọn latigba ti wọn ti gbe lọ si Germany, iroyin kankan ko jade nipa rẹ lati ọdọ awọn ti wọn sunmọ aarẹ orilẹede Naijiria koda bo ṣe lori faran Facebook ni tabi Twitter.

Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari ko ṣ'alaye igba ti Yusuf Buhari yoo pada si Naijiria.

Image copyright Facebook/Presidency
Àkọlé àwòrán Ajalu naa ba Yusuf Buhari ni l'ọjọ ọdun keresimesi l'Abuja

Ni ibẹrẹ osu kinni ni wọn da ọmọ aarẹ naa silẹ ni ilewosan kan l'Abuja lẹyin igba ti ajalu ijamba alupupu baa ninu oṣu kejila ọdun 2017.

Atẹjade kan ti ẹni to n fun aarẹ Buhari ni'mọran l'ori iroyin, Garba Shehu, fi s'ita nigba naa sọ wipe ijamba alupupu naa ṣẹlẹ ni adugbo Gwarimpa to wa ni igboro Abuja ni l'ọjọ keresimesi.

Garba Shehu sọ wipe: "O kan lẹsẹ, lẹyin igba naa o f'arapa l'ori nibi ijamba naa. Bẹẹ naa wọn ṣiṣẹ abẹ fun un nile iwosan kan to wa l'Abuja, ṣugbọn ara rẹ n m'okunsi ni bayii".

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: