Eeyan mẹwa to mu 'Yọllywood' lamilaaka

Omobinrin n wo ere Nollywood

Oríṣun àwòrán, AFP

Nollywood ni ẹgbẹ awọn osere lorilẹ-ede Naijiria, ninu eyi ta ti ri awọn ogbontagiri osere tiata to ti laamilaaka ninu isẹ ti wọn yan laayo.

"Yọllywood" yoo ma fun un yin niroyin nipa awọn osere to jẹ Yoruba lori itakun agbaye BBC Yoruba loorekoore.

Orukọ awọn mẹwaa lara awọn to je ilumọọka ninu ẹgbẹ osere Nollywood, ti wọn jẹ ọmọ Yoruba ni yii:

Odunlade Adekola

Ọmọ bibi ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun, to wa niwọ oorun Guusu Naijiria ni osere naa ise.

Lati kekere lo ti bẹrẹ ere apanilẹrin ninu ile ijọsin. Lara awọn ere to ti se ni ''Sunday Dagboru, Alani Pamọlekun, Mufu Oloosha oko ati Adebayo Arẹmu Abẹrẹ''.

Mide Martins

Ọmọbibi inu gbajugbaja osere, Funmi Martins ni Mide Funmi Martins Abiodun.

Femi Adebayo

Ilu Eko ni wọn ti bi gbajugbaja olosere yii. Ọdun 1995 lo ti bẹrẹ isẹ osere nigba to kopa ninu ere ''Owo Blow''. A si tun mọ ọ si ''Jẹlili'' nitori ipa to ko ninu ere rẹ ''Jẹlili''.

Funke Akindele

Gbajugbaja osere ni arabinrin yii. Fiimu rẹ ''Jẹnifa'' jẹ ilumọọka sinima tawọn eniyan fẹran lati maa wo ni, to si muni rẹrin takiti.

Olaniyi Mikail Afonja

Awọn eniyan mọọ si ''Sanyẹri''. Ere apanilẹrin lo ma nse lọpọ igba, paapaa ninu ere ''Muniru ati Ambali''.

Mercy Aigbe

Ọdun 2001 ni gbajugbaja osere yii bẹrẹ isẹ tiata. O si ti di ilu mọọka fawọn ipa ribiribi to ma nko ninu awọn ere rẹ. Ojulowo Yoruba lo ma n sọ lẹnu.

Gabriel Afolayan

Yatọ si pe o n sere tiata, Gabriel Afolayan tun ma n kọrin ifẹ lọpọ igba. Orukọ rẹ lori itage rẹ ni ''G-Fresh''.

Kunle Afolayan

Idile olosere ni awọn Afolayan lati ilu Agbamu nipinlẹ Kwara. Gbajugbaja adari ere ni, ati wipe Adeyemi Josiah Afolayan (Ade Love) ni baba rẹ, to si jẹ tẹgbọn taburo loun ati Moji Afolayan, Gabriel Afolayan ati

Aremu Afolayan.

Toyin Abraham

Gbajugbaja oserebinrin lo njẹ Toyin Aimakhu tẹlẹ. O bẹrẹ ere tiata ni bii odun marundinlogun sẹhin. Awọn ere re a ma koni lẹkọ. O gbajumọ ninu ere ''se bo o ti mọ'', paapa ninu ere rẹ ''Alakada''.

Muyiwa Ademola

Ọdun 1991 lo bẹrẹ ere tiata, lati igba naa lo si ti lami laaka ninu awọn ere akọnilọgbọn to ma n gbe jade. Lara awọn filmu rẹ ni ''Ori, Ilẹ, J.J, Alapadupe ati Owo Okuta''.