Idibo 2019: Aawọ abẹnu lee koba APC

Ami idamọ APC Image copyright @APCNigeria
Àkọlé àwòrán Ọpọ ipinlẹ lo n koju aawọ abẹnu ninu ẹgbẹ APC lorilẹede Naijiria

Ẹgbẹ oselu APC to n dari ijọba apapọ lọwọ lorilẹede Naijiria ni aawọ abẹnu nba finra ni ọpọ ipinlẹ to wa lorilẹede yi, eyiti ko din ni ipinlẹ mejila.

Awọn aawọ yi, to maa nda lori awọn gomina to n tukọ irufẹ ipinlẹ bẹẹ pẹlu awọn asofin apapọ, si lo ti fẹju sita ni kete lẹyin eto idibo ọdun 2015,

ti ko si tii jẹ rodo nibayi ti eto idibo ọdun 2019 nkanlẹkun.

Ọpọ nkan ni wọn lo sokunfa awọn aawọ naa bii siseowo basubasu, hihu awọn iwa to lodi sofin ẹgbẹ, lila kaka lati di ipo giga mu, sise ijọba lọna ti ko wu ni lori ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn gomina ipinlẹ atawọn asofin apapọ lo saba maa n koju ara wọn.

Awọn irufẹ laasigbo yi si lo ti mu ikede idaduro ninu ẹgbẹ lọwọ tabi ki wọn ni ki eekan ọmọ ẹgbẹ lọ rọọkun nile, to fi mọ ija igboro ati sisọ ọrọ abuku sira ẹni.

Lara awọn ipinlẹ ti aawọ abẹnu nba finra ninu ẹgbẹ oselu APC si ni Ipinlẹ Gombe, Oyo, Ogun, Plateau, Bauchi, Borno, Ondo, Kogi, Niger, Kaduna, Kano ati bẹẹ bẹẹ.

Diẹ ninu awọn ipinlẹ ti omi ẹgbẹ oselu APC ko ti toro ree:

1)Oyo: Gomina Abiọla Ajimọbi ati Minisita feto ibaraẹnisọrọ, Adebayọ Shittu ngbena woju ara wọn

2)Kaduna: El Rufai ati Sẹnats Shehu Sanni nwọ Sokoto kanaa eyi to n fa laasigbo lọwọ

3)Gombe: Gomina Danjuma Goje ati Sẹnatọ Usman Nafada kii foju rinju

4)Ogun: Gomina Ibikunle Amosun ati Sẹnatọ Ọlamilekan Adeọla dijọ nse fanfa

5)Plateau: Gomina Simon Lalong ati minisita fọrọ ere idaraya, Solomọn Dalung nse bii ata ati oju

6)Bauchi: Gomina Muhammed Abubakar ati Minisita feto kọ, Adamu Adamu kii ri imi ara wọn laatan

7)Ondo: Gomina Rotimi Akeredolu ati igbimọ alasẹ ẹgbẹ APC nipinlẹ naa nse gbolohun asọ eyi to bẹrẹ latigba ipalẹmọ fun ibi gomina nipinlẹ naa.

8)Kogi: Gomina Yahaya Bello atawọn ọmọ ile asofin apapọ lati ipinlẹ naa kii ri imi ara wọn laatan to fi mọ Sẹnatọ Dino Melaye

9)Niger: Gomina Sani Bello ati Sẹnatọ meji, Aliyu Abdullahi ati David Umaru dijọ nfori gbariS

10)Kaduna: Gomina Nasir El Rufai ati Shehu Sani pẹlu awọn ọmọ igbimọ alasẹ ẹgbẹ APC nipinlẹ naa ntutọ si ara wọn loju

11)Kano: Gomina Abdullahi Ganduje ati Sẹnqatọ Rabiu Kwankwaso nse bii ọmọ iya awusa.

Eyi si lo mu ki aarẹ Muhammadu Buhari kede ifilọlẹ igbimọ kan ti oloye Bọla Tinubu ko sodi lati doola aawọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC jakejado Naijiria.

Njẹ oju wo lawọn ọms ilẹ yi fi wo aawọ abẹnu to n mi omi alaafia ẹgbẹ oselu APC logbologbo lawọn ipinlẹ kan lorilẹede yi ati ipa to lee ni lori idibo 2019 fẹgbẹ oselu naa.

onwoye awujọ kan to tun jẹ onimọ nipa eto oselu, Ọmọwe Dikrullahi Yagboyaju salaye pe kii se tuntun ki aawọ wa ninu ẹgbẹ oselu kan, ọna ti wsn ba gba yanju rẹ lo se koko.

Ẹ gbọ Ọmọwe Yagboyaju siwaju sii:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIdibo 2019: Aawọ abẹnu lee koba APC